07/09/2025
*ÌJỌ K&S ONITẸSIWAJU GBOGBO ÀGBÀIYE AYỌ NI O*
*ÌWÉ ÌLÉ ẸKỌ ÌSÌNMI TÌ ÁWỌ́N ÀGBÀ, LÁTI ỌDỌ BÀBÀ ALADURA PRO E.A ALOGBO.*
*Ọ̀SẸ̀ KẸRINDINLOGOJI*
*ỌJỌ: ỌJỌ KEJE OṢÙ KẸSÁN, 2025*
*ÀKORI: ÌGBÀGBỌ ÀWỌN BÀBÁ WÁ (ÀPÁ A)*
*ÀYỌKÀ BIBELI:* HÉBÉRÙ 11:17-35
*AKỌ́SORÍ:* *"Olufẹ mo ti gbìyànjú t**i lati kọwe sí yin nipa igbala ti a jọ ní, nigba ti mo ri wipe o di dandan kí n kọ iwe si yín, ki n rò yin pe kí ẹ máa já fún ìgbàgbọ tí Ọlọrun ti fún àwọn ènìyàn Rẹ mímọ lẹẹkan soso". JUDA 1:3.*
*ÌPÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́*
Ogo ni fun Ọlọrun ti o mu ìjọ Kerubu ati Serafu de ibi to de loni. Ayẹyẹ ọgọrun ọdun (*100 years*) wa ree o si yẹ ki a dupẹ lọwọ Ọlọrun àwọn baba wa. Amọ sa, ko si ariyanjiya lori wipe iran yi nilo lati pada s'ọdọ Ọlọrun ati s'inu ìgbàgbọ àwọn Baba wa. O yẹ ki a ji iji-ododo bi ti igbaani. Bi a ba tun fẹ ni iriri isẹ-akin ti ìjọ se bi ti àtijọ gẹgẹ bi iwe-orin wa kan ti wi (Kerubu ma gb'ode kan, kosi 'ru eyi ri........)
Jiijo!
A gbọdọ kiyesi wipe atunpa àwọn baba wa la tan ni ibi ìkọkọ, ti a mu ki o mọlẹ nipasẹ iwa mímọ ni gbangba; to si n jo t**i nipasẹ ìyasọtọ ati omije ninu adura ti a n gba lati ran àwọn ẹlòmíràn lọwọ. Sibẹ, ko see se ki ohun ti a sọ di imọlẹ kedere nipasẹ ikaanu àwọn baba nla wa mu ki atunpa awa naa jo geere t**i lae. Iran wa yi n fẹ ki atunpa wa mọlẹ t**i aye ṣugbọn a ko fẹ f'ara ṣiṣẹ nibi ikọkọ. A ti gbàgbé wipe ohun ti o tan imolẹ s'ori atunpa àwọn baba wa ni adura to gbona ti a se ni ibi ìkọkọ pẹlú ìgbàgbọ pọnbele ninu Ọlọrun ati Ẹmi rẹ.
Gẹgẹ bi Abrahamu ti jẹ baba-nla akọkọ fun àwọn ọmọ Heberu ti gbogbo àwọn ẹlẹṣin Juu, Kristiani ati àwọn ẹṣin miran si n b'ọwọ ati ọlá fun un, bẹẹ naa ni a gba Mose Orimọlade Tunọlase gẹgẹ bi ẹni to da Ẹgbẹ Mímọ Kerubu ati Serafu silẹ, to si tipa bẹẹ jẹ baba-nla wa akọkọ, ati ọkàn gboogi lara àwọn akikanju ati akọni ìgbàgbọ ni ilẹ Naijiria ati ni gbogbo ile-adulawọ Afirika.
Amọ sa, o seni laanu loni pe awon iran Kristiani kan ti dide to dabi wipe wọn jẹ ope nipa awon ohun ati iran to ti kọja. Ọrọ yi buru jai jùlọ paapa laarin àwọn ọdọ ninu ijọ Kerubu ati Serafu. Iwadi fi han wipe ọpọ àwọn ọmọ-ijọ wa loni lo ni ìmọ perete tabi ti wọn jẹ alaimọ̀kan nipa isẹ-akin ti àwọn akọni wa to ti kọja ti se to mi orílẹ-èdè Naijiria t**i fun Kristi, to si la ọnà fun isọji nla ti Pentikosti ni ilẹ adulawọ - àwọn Baba ìjọ wa. Ọrọ yi ri bẹẹ nitori wipe wọn ko ni ibaṣepọ pẹlu ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ itan nipa isẹ-akin ti agbara ati ogo nla ti wọn fi j'ogun silẹ fun wa, eleyi to f'igba kan jẹ okun ati agbara àwọn baba wa ninu ìgbàgbọ yi.
Nitori naa, bi ìjọ wa ti n s'ajọyọ ọgọọrun ọdun (1925-2025) bayi, a n gbiyanju lati mu wa si iranti, ìgbàgbọ, adura ati suuru àwọn baba wa ninu ìgbàgbọ papa jùlọ, ẹnití o jẹ oludasilẹ isẹ-iransẹ nla wa yi - Ẹni-ọwọ, Mose Orimọlade Tunọlase. A n tan imọlẹ si igbesi aye rẹ lati kin ọrọ yi lẹhin, nitori wipe o jẹ ọkàn lara àwọn awọsanmọ ẹlẹri ti Aposteli Paulu sọ pe o rọgba yi wa ka ninu episteli rẹ si àwọn ara ninu Oluwa to wa ni Heberu. Heb. 12:1.
A bi Mose Orimọlade Tunọlase ni odun 1879 si idile Ọmọ'ba Ode Sodi [1] ti adugbo Okorun ni ilu Ikarẹ-Akoko, l'apa ìwọ̀-oòrùn ilẹ Naijiria. Ọdọmọkunrin Orimọlade a maa jọsin n'ile-ijọsin St. Stephen's Anglican Church (C.M.S)-to jẹ ile-ijọsin kan soso to wa ni ilu Ikarẹ l'akoko naa. A maa digba da kọrin ninu ile-ijọsin, nigbakugba ti o ba sin se eyi, ina agbayanu kan a maa mọ'lẹ ninu ile naa ti iro re yoo si kun gbogbo ile-ijọsin bi wipe ẹgbẹlẹgbẹ eniyan lo n kọrin níbẹ.
Lọjọ kan n'irufẹ akoko bayi, ajoji agbayanu ina ati ohun yi lo mu ki Alufa to wa lori ìjọ naa wọ'le wa lati se'wadi ohun to n ṣẹlẹ. Ṣugbọn nigbati o si ilẹkùn, ko ri ẹnikẹni ayafi ọdọmọde-kunrin ti o joko to si n da kọrin laisi ẹlòmíràn níbẹ - sibẹ, o dabi wipe ọgọọrọ eniyan lo n kọrin l'ohun kan ati ede kan.
*ÁTUPÁLẸ Ẹ̀KỌ́:*
*Awon ohun ti ko wọpọ lara ẹlòmíràn ti Mose Orimọlade ni.*
*a. O jẹ àpẹẹrẹ Kristi.* O wa s'aye fun iṣẹ ti a ran an nikan eleyi ti gbogbo igbesi aye rẹ da le lori, ti o si ku fun pẹlú. Bakan naa gẹgẹ bi Jesu, ko t'ọwọ bọ ohun afẹ-aye miran - ko n'iyawo, ko bi'mọ (A n sọ nipa àwọn ọmọ ti ara rẹ). Sibẹ sibẹ, bi ti Olugbala naa, àwọn Ọmọ Mose ko l'onka loni kaakiri nibi gbogbo l'agbaye. Johanu 18:37.
*b. O kun fun Ẹmi Mimọ.* O daju wipe o kun fun ifami-ororoyan to ga pẹlú Ẹmi Mímọ ati agbara. Ise 10:38. Eleyi lo maa n mu wa si ojusẹ ni gbogbo ibi to ba lọ gẹgẹ bi Ọlọrun ti n gba ọwọ rẹ ṣiṣẹ, ti O sin ti ọrọ ati adura rẹ lẹhin pẹlú iṣẹ-àmi ati iyanu to n tẹ le e. Maku 16:15-20.
*c. O jẹ'gbadun isẹ-iransẹ àwọn angeli púpọ-pupọ.* Orimọlade jẹ'gbadun isẹ-iransẹ àwọn angeli lẹkunrẹrẹ lati igba to wa ninu oyun. Heb. 1:13-14. O wa l'akọsilẹ pe l'ọjọ kan, angeli rẹ ran iya re lọwọ lati gbe igi-idana to wuwo to di sile ru u. Ati pe bi oun ti jẹ arọ, irinke-rindo rẹ ni áwọn angeli ran lọwọ eleyi to mu ki o maa farahan ni ọpọlọpọ ibi laisi iranlọwọ ẹnikẹni rara, lai lọ oko pẹlú. Orin 91:11- 12 se afiwe pelu Ise. 8:39.
*d. Tirẹ jẹ isẹ-iransẹ áwọn Aposteli (Pentikostí)* Baba to n gbadura la mo o si (Baba Aladura), gbogbo isẹ-iransẹ rẹ lo si da lori adura ati àwẹ pọnbele NIKAN SOSO. A yọnda ki iṣẹ-àmi ati iyanu maa ti ọwọ rẹ sẹ gẹgẹ bi ti àwọn Aposteli igbaani. Ise. 14:3. Sibẹ, ko pa ohunkohun pọ mọ ojulowo ihinrere Oluwa wa Jesu Kristi ati adura; ko si abusa'ri, àwọn amugbalẹgbẹ adura bii agbọn, ikoko amọ, akanse ọsẹ, t'ewe t'egbo, etutu pẹẹ-pẹẹ-pẹ, ko si pe a n bẹ angeli lọwẹ, bibere ọrọ lọwọ àwọn ẹmi oju-ọrun, ko gbe apoti-eri ati bẹẹ bẹẹ lọ. A ko ri àwọn nkan wọnyí lọwọ rẹ; bi-o-tilẹ-jẹ-wipe o tan abẹla lẹẹkan ri, sibẹ nse lo kan lo o fun ami afojuri ti kiise fun eto adura. Bi-o-ti-wu-ki-o-ri, nigba aye rẹ, abẹla s'ọwọn púpọ l'akoko yi, nitori naa, titan abẹla ko le jẹ koko pataki iṣẹ-ìsin ìjọ to gbe kalẹ ati iṣẹ adura oun funrarẹ pẹlú.
*e. A da ọpọ ifamiororoyan le e lori, ti ago re si kun akunwo silẹ.* Bi-o- tilẹ-jẹ-wipe a ko le fi gbogbo ẹnu sọ wipe Ọlọrun da ifami-ororo le Orimọlade l'ori lail'oduwon bi ti Jesu Kristi, o daju wipe o ni ifamiororoyan to ga, to n san, eleyi ti ẹrí rẹ jẹyọ nipa ọgọọrọ àwọn òjíṣẹ Ọlọrun ti wọn ti ara rẹ dide ni orile ede wa Naijiria nikan. Fun àpẹẹrẹ, ijo onirapada (The Redeemed Christian Church of God), ti a ti ọwọ Pa Josiah Akidayọmi da silẹ lo jade lati inu C&S, oludasilẹ ìjọ Deeper Life Bible Church, Pasito W. F Kumuyi lo ti f'igba kan ri jẹ ọmọ ìjọ Kerubu ati Serafu; bẹẹ naa ni Bishobu Dafidi Ọlaniyi Oyedepo ti ìjọ Asẹgun (Living Faith Church a.k.a Winners' Chapel); ka saa mẹnu ba diẹ kiun. Oun ni ọkùnrin ojisẹ-Ọlọrun adúláwọ̀ akọkọ to bẹrẹ gbogbo isẹ-iransẹ àwọn ìjọ Aposteli ati Pentikosti jake-jado orilẹ - ede Naijiria ati ilẹ-adulawọ Afirika lapapọ. T**i di oni oloni, o fẹrẹ jẹ wipe gbogbo àwọn òjíṣẹ Ọlọrun to muna-muna ni awon ile-ijọsin to lami-laaka loni ni Naijiria ati rekọja lo ni gbongbo wọn ninu iṣẹ iransẹ Mose Orimọlade Tunọlase.
*L'ÁKÓTÀN*
Itan Mose Orimọlade Tunọlase la gbọdọ sọ fun iran yi lati se koriya fun wọn ati lati ru ìgbàgbọ, adura ati suuru wa s'oke gẹgẹ bi Kristiani igbẹhin-aye ati ọmọ-ogun Kristi l'akoko yi. Áwọn ìjọ iran wa ati Kristiani akoko yi lo ni ohun púpọ lati kọ lara igbesi aye ati isẹ-iransẹ Mose Orimọlade.
*SHALOM!*
*AYỌ NI O*