Itumo Ese Oro Bibeli "The Meaning Of The Bible Verse""

Itumo Ese Oro Bibeli "The Meaning Of The Bible Verse"" A gbe abala yi kale lati mu itesiwaju ba igbagbo wa ninu oro Olorun. Ati sise awon alaaye ese oro Bibeli yi fun imudagba ati imuduro Igbagbo wa.

Jesu ni ona otito ati iye, gba Jesu loni, ola le peju.......... JESUS IS LORD
01/11/2025

Jesu ni ona otito ati iye, gba Jesu loni, ola le peju..........
JESUS IS LORD

28/10/2024
28/10/2024

*๐Ÿซต๐ŸปAGBEYEWO ESE(VERSE) ORO TONI.*

๐Ÿ“–PSALM 40:6.....
*โœ๏ธ _EBO ATI ORE_ IWO* KO FE*****

๐Ÿ’ก *ATUPALE!!!!!!!!*
Ti aba wo Psalm yi,a'o ri wipe oye ye oni psalm yii wipe awon ebo ati awon apere eto ti Olorun n beere fun ninu ofin Re ko pe ninu ara won,beeni ko le ropo iyonda ara eni tokan-tokan ati igboran to tinu okan wa si Olorun [wo 1Sam 15:22; Isa 1:11-17; Jer 7:22-23; Mika 6:6-8].

๐Ÿซ Bakan naa,awon onigbagbo majemu tuntun,le kopa ninu Iribomi ti odo,Ounje ale Oluwa,Ijosin,tabi orin Iyin lai ya okan won soto fun Olorun ati awon ase oro Re.

๐Ÿฆป๐Ÿป Kosi awon eto esin ti o le ropo igboran igbagbo (se afiwe Rom 1:5)........

โ›ช The Seed Of Faith Evangelical Ministry Int'l (sofem)

โœ๏ธ JESUS IS LORD.

20/08/2024

โœ๏ธ AGBEYEWO ESE (VERSE) ORO OLORUN TONI....

๐Ÿ“– PSALM 149 vs 6
๐Ÿ’ฅKI IYIN OLORUN KI O WA LI ENU WON, ATI IDA OLOJU MEJI LI OWO WON.

๐Ÿ–๏ธATUPALE:--
โœ๏ธEse yi so nipa awon akitiyan olododo ni ona meji: ijosin ati ogun ti emi.

โœ๏ธItara wa lati yin Olorun ni itara lati dojuko ijoba Satani gbodo tele.

โœ๏ธIjoba Olorun ko le fidimule ni ekunrere t**i di igba ti a ba ba segun gbogbo agbara okunkun.

โœ๏ธA gbodo dide lodi si agbara Esu nipa gbigbe igbe-aye ododo, igbagbo, ki a mu ida Emi (e.n.p. oro Olorun),ki a si gbadura ninu Emi (Ef 6:11-18).

โœ๏ธNi igba ikehin fun iyin Olorun a o kopa ninu sise idajo aye ti ko ronupiwada to n sodi si Kristi (Kor 6:2-3; Ifih 18:20;19:1-4,11-21)...

โ›ช FROM The Seed Of Faith Evangelical Ministry Int'l (sofem).

19/02/2024

๐Ÿ–Š๏ธ [AGBEYEWO ESE (VERSE)ORO OLORUN TONI]>>>
๐Ÿ“–ROM 12:1-2:--NITORINA MO FI IYONU OLORUN BE YIN,ARA, KI EYIN KOFI ARA YIN FUN OLORUN NI EBO AAYE MIMO, ITEWOGBA, EYI NI ISE-ISIN YIN TI O TONA. 2) KI E MA SI DA ARA YIN PO MO AIYE YI: SUGBON KI E PARADA LATI DI TITUN NI IRO-INU YIN, KI EYIN KI O LE RI IDI IFE OLORUN, TI O DARA, TI O SI SE ITEWOGBA, TI O SI PE.

๐Ÿซต ALAYE KUKURU**
๐Ÿ“’FI ARA YIN FUN OLORUN NI EBO AAYE. "Awon onigbagbo gbodo ni itara lati inu okan kan lati wu Olorun ni ife, ifokansin, iyin ati iwa mimo, ati lati fi awon eya ara won rubo fun ise-isin Re.

๐Ÿ‘‰๐ŸพIfe okan ati adura wa ti o ga julo, ye ki o je lati gbe igbesi aye iwa mimo ati lati je itewogba ni owo Olorun.
๐Ÿ”ท Eleyii gba ki a ya ara wa soto kuro ni ara aye, ki a si maa sunmo Olorun sii ni gbogbo igba.
๐Ÿ”ท A gbodo gbe fun Olorun, ki a sin In, ki a gboran si I, ki a duro ni iha Re lati koju ija si ese, ki a duro fun ododo, ki a koju ija si ibi, ki a si korira re, ki a se ise aanu fun elomiran, ki a se afarawe Kristi, ki a to O leyin, ki a sin In, ki a rin nipa Emi mimo, ki a si kun fun Emi Mimo

๐Ÿ‘‰๐Ÿพ A gbodo fi ara wa fun Olorun gege bi oku si ese ati gege bi tempili Emi Mimo (1Kor 6:15,19).

๐Ÿ“’Rom 12:2:-- "KI E MA SI DA ARA YIN PO MO AIYE YI: SUGBON KI E PARADA.....

๐Ÿ‘‰๐ŸพOrisirisi ni awon ohun ti PAULU n'so ninu ese yii.
๐Ÿ”ท A gbodo mo pe ilana aye isinsinyi ibi lo je (Ise. A 2:40;Gal 1:4).
๐Ÿ”ท O si wani abe akoso Satani (Joh 12:31;1Joh 5:19).

๐Ÿ‘‰๐Ÿพ A gbodo dide lodi si emi aye yii ti o n joba ti o si gbaju-gbaja, ki a si kede otito ati odiwon ododo Oro Olorun ti o je ayeraye, nitori ti Kristi (1Kor 1:17-24).

๐Ÿ‘‰๐Ÿพ A gbodo pegan, ki a si ko ohun ti o je ibi, ki a si feran ododo (Rom 12:9;1Joh 2:15-17;Heb 1:9).
๐Ÿ”ท Ki a si kรฒ lati fi ara wa sile fun orisii iwa ti aye ti o yi ijo ka nigba gbogbo.
๐Ÿ”ท Gege bi iwora, imo-ti-ara-eni-nikan, ero ti ara, idogbonsi ona oselu lati de ipo agbara, ilara, ikorira, igbesan, aimo, oro ti ko dara, ere idaraya ti aiwa-bi-Olorun, iwa ibaje, aseju, iwa buburu, oogun oloro, oti lile ati ikegbe pelu aye.

๐Ÿ‘‰๐Ÿพ A gbodo jeki okan wa ba ona ti Olorun n'gba ro nu mu (1Kor 2:16;Fil 2:5).
๐Ÿ”ท Nipa kika ati sise asaro ninu oro Re (O.D 119:11,148; John 8:31-32; 15:7).
๐Ÿ”ท A gbodo je ki a se amona eto wa, ilepa wa, ati erongba wa nipa awon otito ti i oro Olorun, ti won si je ayeraye, kii se nipa akoko yii ti o je kiki ibi, ti o wa fun igba die, ti o si n koja lo.
๐Ÿ“ ARA E'SE ASARO LORI ORO YI, MO GBADURA KI EMI MIMO FUN WANI ITUMO TO PE YE SI AMIN.

๐Ÿฃ FROM The Seed Of Faith Evangelical Ministry Int'l (SOFEM).

2024 The year of a new name.

26/01/2024

๐Ÿ“š SISE AGBEYEWO ESE ORO OLORUN YI...
๐Ÿ“– 1TESSALONIKA 2:18 (Nitori awa fe lati to yin wa, ani emi Paulu leekini ati leekeji;Satani si de wa li ona.

๐Ÿ‘Š๐Ÿป AGBEYEWO

17/01/2024

๐Ÿ‘Š๐Ÿป ATUPALE ESE ORO OLORUN YI.

๐Ÿ“– JAKOBU 4:1,3 ****
๐ŸซดNibo ni ogun ti wa, nibo ni ija si ti wa larin yin? lati inu eyi ha ko? lati inu ifekufe ara yin, ti njagun ninu awon eya-ara yin. vs 3" Eyin bere e ko si ri gba, nitoriti enyin si i bere, ki enyin ki o le lo o fun ifekufe ara yin.

โš™๏ธ ATUPALE..........

๐Ÿ“š NIBO NI OGUN TI WA, NIBO NI IJA SI TI WA LAARIN YIN?
๐Ÿ–Š๏ธ Ohun pataki ti o n fa ijangbon ati ija ninu ijo ni ife-okan fun ipo, ola, ogo, agbara, igbadun owo ati nini ola ju.
๐Ÿ–Š๏ธ Tite ife-ara-eni nikan lorun, eyi awa se pataki ju ododo ati ife Olorun lo (s.a Mak 4:19 "Aniyan aye, ati itanje oro, ati ifekufe ohun miiran si bo sinu won, won fun oro naaa pa, be ni o si je alaileso)
๐Ÿ–Š๏ธ Nigba ti eleyii ba sele, a mu ki ija imo ti ara-eni-nikan ki o sele ninu ipejopo.
๐Ÿ–Š๏ธAwon ti oran naa ba kan a'fi ara won han ni eni ti kii se ti Emi, ti won ko si si ninu ijoba Olorun (Jud 1:16-19"Awon wonyi ni awon ti n kun,awon alaroye,ti n rin nipa ifekufe ara won;enu won a maa so oro ihale,won a maa s'oju saaju nitori ere 17...Sugbon eyin olufe,e ranti awon oro ti a ti so saaju lati owo awon Aposteli Oluwa wa Jesu Kristi 18...Bi won ti wi fun yin pe,awon elegan yoo wa nigba ikehin,ti won o maa rin gege bi ifekufe aiwa-bi-Olorun ti ara won. 19... Awon wonyi ni awon eni ti n ya ara won si oto,awon eni ti ara,ti won ko ni Emi).

๐Ÿ“š (Jak 1:3) EYIN BEERE, E KO SI RI GBA***
๐Ÿซด Olorun ko lati dahun adura awon ti won nifee ohun rere, ife faaji, ati ife lati ni ola, agbara tabi oro fun ti ara won nikan.
๐Ÿซด Gbogbo wa gbodo se akiyesi nitori Olorun ki yoo teti si adura wa ti a ba ni okan ti o kun fun ife imo-ti-ara-eni-nikan.
๐Ÿซด Iwe mimo so fun wa wipe adura awon olododo nikan ni Olorun maa n tewogba (O.D 34:13-15;66:18-19),ti awon ti won kepe E ni otito (OD 145:18), ti awon ti won ronupiwada ni aisetan, ti won si re ara won sile (Luk 18:14-15), ati ti awon ti won beere fun ohunk'ohun gege bi ife Re (1Joh 5:14).

๐Ÿ™๐ŸฝAGBARA TI KI JE KI ENIYAN YAPA SI IFE OLORUN, KI EMI MIMO GBE WO YIN

Address

Osogbo
CHRISTIANITY

Telephone

+2349053317152

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Itumo Ese Oro Bibeli "The Meaning Of The Bible Verse"" posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Place Of Worship

Send a message to Itumo Ese Oro Bibeli "The Meaning Of The Bible Verse"":

Share