24/05/2026
OSE KEJO, EKO KEJO (24th MAY,2026) KOTA KEJI
Akori eko: OKO ATI IYAWO FI OJU KAN ARA WON
Bibeli kika: Gen 24:61-67
Ese akosori: “Rebeka si gbe oju soke, nigba ti o ri Isaaki, o sokale lori ibakasie"(Gen 24:64)
Oro saaju eko
Rebeka ti gba lati ba iranse Abrahamu lo si Kenani lati lo pade oko iyawo. Awon obi re naa si ti yanda lati jowo Omo won fun Isaaki gege bi aya. Won mu irinajo won pon lati lo ipade oko iyawo. Awon eniyan Rebeka sure fun un, won si ran an tele iranse Abrahamu (Gen 24:59-61)
Alaye lori eko
“Isaaki si jade lo se asaro ni oko ni asale, o si gbe oju re soke, o si rii, si kiyesi, awon ibakasie n bo wa”(Gen 24:63). Isaaki je eni ti n se asaro; o kuro ni awujo ni ilu, o lo si inu oko nibi ti ko si ariwo lati di I lowo lati lo se asaro. Awa omo Olorun, a gbodo maa fi aye sile fun akoko idakeje lati ka oro Olorun, ki a se asaro lori awon eko oro Olorun, ki a si gbadura. Asaro sise nibi ti o dale roro se Pataki fun awa omo Olorun. A le ji ni arin oru lati se asaro tabi ki a lo sinu oko tabi ibikibi ti ariwo ko si lati ba Olorun jiroro po ki a si se asaro lori oro Re (Orin Dafidi 1:2; 77:12; 119:15,27,48,97,148; 143:5).
Kete ti Rebeka ti ri Isaaki ni onfa ife ti fara han laarin won. Ni ese 65, o bere lowo Elieseri pe, “… okunrin ewo ni o n rin bo ni oko lati wa ko wa nni”? Ti Omo Olorun ba wa oju Oluwa nipa ife Olorun ninu ohunkohun, paapa nipa igbeyawo, ti Olorun ba to o sona, ti o si gbe egungun bi egungun ara re, ife to jinle maa n fara han ninu igbeyawo bee. Eyin apon ati omidan, e jowo e bere lowo Olorun ki e to gbeyawo tabi ni oko. Loruko Jesu, e o ni gbe igi eleera. (Amin)
Nigba ti Rebeka se awari pe oko oun ni o n bo wa ninu oko, o mu iboju lati bo oju re. Eyi fihan wipe omoluabi ti ko ni agbaju, ti a ko nile ti o si gba eko ni o nse (ese 65). Opolopo awon Omobinrin ode oni ni ko ni itiju mo, won be, won a rin ihoho; olaju ti baye opolopo awon Omobinrin je loni, ko si eko lara won. Awa omo Olorun tooto gbogbo yato si awon omo aye.
Iranse naa si rohin irinajo re fun Isaaki Omo oga re. Elieseri je Omo odo ti o mo ise nje, ti o si kunju osuwon. O se aseyori ninu ise ti a gbe le e lowo. Awa iranse Olorun ati gbogbo omo Olorun lapapo, se a kunju osuwon ninu ise iranse wa?(ese 66). Rebeka jasi itunu fun Isaaki oko re. Aya rere lodede oko (ese 67).
E je ki awon omode ati agba mo pe titele itoni Olorun maa n mu aseyori wa ninu ohun gbogbo.