07/04/2025
*BIBA OLORUN PADE LOJOOJUMO (NBC YORUBA)*
*MONDAY, APRIL 7, 2025*
*EŞĘ WA TI PA OJU OLORUN MQ*
*YBH 616: Mo Fi Gbogbo Re Fun Jesu*
1.MO fi gbogbo re fun Jesu
Patapata laiku kan;
Ngo ma fe ngo si gbekele,
Ngo si ma ba gbe t**i,
Mo fi gbogbo re,
Mo fi gbogbo re,
Fun O Olugbala mi ni
Mo fi won sile.
2.Mo fi gbogbo re fun Jesu,
Mo si wole lese Re;
Mo fi afe aiye sile
Jesu jo gba mi wayi,
Mo fi gbogbo re, etc.
3.Mo fi gbogbo re fun Jesu,
Jesu se mi ni tire;
Jek' Emi Mimo s' eleri
P' emi tire, 'wo t' emi.
Mo fi gbogbo re, etc.
4.Mo fi gbogbo rè fun Jesu
Mo f' ara mi f’ Oluwa;
F' ife at' agbara kun mi,
Si fun mi n' ibukun Re.
Mo fi gbogbo re, etc.
5.Mo fi gbogbo re fun Jesu,
Okan mi ngbona wayi;
A! ayo igbala kikun!
Ogo ni f’ Oruko Re.
*Ese wura:* Sugbon aisedeede yin ni o ya yin kuro lodo Olorun yin, ati ese yin ni o pa oju Re mo kuro lodo yin, ti Oun ki yoo fi gbọ. Isaiah 59:2
*Bibeli Kika: Isaiah 59:1-8*
[1] KIYESI i, ọwọ́ Oluwa kò kuru lati gbàni, bẹ̃ni eti rẹ̀ kò wuwo ti kì yio fi gbọ́.
[2] Ṣugbọn aiṣedede nyin li o yà nyin kuro lọdọ Ọlọrun nyin, ati ẹ̀ṣẹ nyin li o pa oju rẹ̀ mọ kuro lọdọ nyin, ti on kì yio fi gbọ́.
[3] Nitori ọwọ́ nyin di alaimọ́ fun ẹ̀jẹ, ati ika nyin fun aiṣedede, ète nyin nsọ eke, ahọn nyin nsọ ibi jade.
[4] Kò si ẹniti nwá ẹtọ́, bẹ̃ni kò si ẹniti ndajọ ni otitọ: nwọn gbẹkẹle ohun asan, nwọn nsọ eke; nwọn loyun ikà, nwọn mbí iparun.
[5] Nwọn npa ẹyin pamọlẹ, nwọn nhun okùn alantakùn: ẹniti o jẹ ninu ẹyin wọn yio kú, ati eyi ti a tẹ̀ bẹ́ ọká jade.
[6] Okùn wọn kì yio di ẹwù, bẹ̃ni nwọn kì yio fi iṣẹ wọn bò ara wọn: iṣẹ wọn ni iṣẹ ikà, iṣe ipá si mbẹ li ọwọ́ wọn.
[7] Ẹsẹ wọn sare si ibi, nwọn si yara lati tajẹ̀ alaiṣẹ̀ silẹ: èro wọn èro ibi ni; ibajẹ ati iparun mbẹ ni ipa wọn.
[8] Ọ̀na alafia ni nwọn kò mọ̀; kò si idajọ kan ninu ìrin wọn: nwọn ṣe ipa-ọ̀na wiwọ́ fun ara wọn: ẹnikẹni ti o ba tọ̀ ọ kì yio mọ̀ alafia.
_______
Bi ododo se n gbe orile-ede leke, ni ese n fi igba gbogbo je egan fun gbogbo eniyan (Owe 14:34).
Eyi sapejuwe iwa ibaje awujo ti Orile-ede Isreli ti o se okunfa oko igbekun won. Awọn ese orile-ede naa pa oju Olorun mo kuro lodo wọn.
Ese maa n se idena fun adura lati gba. Awọn ese on ba awọn ọmọ Isręli finra ni iwonyii: ipaniyan, p**a, aiṣododo ati gbigbimo ibi. Awọn işesi won dabi ti ejo oloro, nitori won n pa ara wọn lara, wọn si n rin ona ibi nigba gbogbo.
Isaiah je ki o han kedere gege bi awọn eniyan ti le riran nipase owu alantakun bee gege ni Olorun se maa n wo iwa ibi ti awọn eniyan n hu, O si n se idajo won. Wolii naa ran awọn orileede yii leti wi pe Olorun le e gba wọn, bi wọn tile wa ni ipo ti o le.
O ni agbara, apa Rẹ ko kuru, O si n bikita. Eyi tumo si pe Isreli nilo lati kepe Olorun, Yoo gba wọn, ti won ba lee mu aiṣedeede wọn kuro ki won si gba ododo.
Gege bi o ti ri ni akoko Isaiah, ese ni ipa kan naa lori awọn ẹlese. O maa n mu iparun wa, o maa n di alaafia lọwọ, nigbeyin, o maa n fa iyapa patapata kuro lodo Olorun.
Nitori naa, aaye kan soso ti o daju ti o le gbe gbogbo ese re lo ni ibi agbelebu Jesu Kristi nipasę adura idarijin.
Nje o ni ese kan pato ti on ba waya-ija ti o dabi pe o ti je gaba lori aye re?
Jewo re fun Kristi lonii; olododo ati olotiito ni Olorun lati darijin ọ ati lati wę o nu kuro ninu gbogbo aiṣododo.
*Woye:* Ko si iru igbadun ti a le maa gbadun ni aye yii, IKU ni ere ese.
*Ronu:* O ko lee ri oju Olorun ti o ba n tęsiwaju ninu ese.
*Fi Si Işe:* Takete si ese; iwo yoo maa ri oju Olorun.
*Gbadura:* Boju wo mi Oluwa, ki O si saanu fun mi, mase yi oju Re pada kuro lodo mi.
*Gbadura:* Oluwa, pelu igboran mi, mo tilekun orun apaadi, mo gba iye.
*Gbadura fun awon Eni-Owo wonyi, idile ati awọn ọmọ ijo Olorun:* Jonathan O. Ihwighwu, Amukpe; Odewole Niyi, Kaduna; AkindeleAkinkunmi K. T., Ogbomoso; Ukachukwu T.O.C. Eziome; Atumunaonye P.W.C., Inyishi; Ogundiran G. A., Ondo; Aremu D.T., Ogbomoso; Odeleye A.O., Ogbomoso; Olopade J.A., Ogbomoso; Adeniregun S.A., Eko; Ishola D.M., Obagun; Adeniran O.O., Iyeku; Nwachukwu C.N., Rivers; Micheal Nwankwo, Umuoye; Dorcas Adebayo, Kisi; Paul Adeyemo, Katsina; Excellent M. Kuryas., Zaria; Okodase J. Edafe, Delta; Oladele O.P., Eko; Bolaji Odejide, Ilorin; Francis A. Showemimo, Abeokuta.
*KBJL: Samueli Keji 20-22*