08/02/2026
Lehin iku esin, ti pidan-pidan, Joanne Schiebel, Oluko Six and Seven Books Of Moses ku.
Pidan Pidan alagbara miiran ni ilu Amerika, ti oruko re nje D Lawerence, tun iwe Six and Seven Book Of Moses te. Ti o si se aseyori ni pinpin iwe naa kakiri gbogbo ilu Amerika lati so ihinrere Kristi di asan.
Okiki D Lawerence tan kakiri, debi wipe, awon omo ehin re si pupo gidi gan. Oga Jesu (Greater Jesus) ni D Lawerence pe ara re, ti awon omo ehin re si gba gbo Nitori awon ise ami ati iyanu ti Jesu se naa ni D Lawerence fi agbara iwe idan Six and Seven Books Of Moses se.
Jesu rin lori omi, D Lawerence naa rin lori omo.Jesu so omi di Waini, D Lawerence na so omi di Waini.Awon nkan wonyi, ti o se pelu agbara okunkun inu iwe na, jeki opolopo awon eyan gbagbo, won si royin re kakiri wipe, Eniti o ju Jesu lo(Greater Jesus) ni D Lawerence. Opo awon eyan si to wa fun igbala.
Ni odun 1930, D Lawerence kede re kakiri Amerika, wipe, Ki gbogbo aiye ba le mo wipe, owun ni olugbala araye ti o ju Jesu lo. Owun ma ku fun ojo meta, owun a si jinde pada ni ojo keta. Nitoto o si ku, egbegberun awon eniyan si pejo si ibiti won sin si lati ojo kinni t**i di ojo keta ti o so wipe, ohun a jinde. Nigbati o di ojo keta, saare bere sini mi, Bi wipe eniti o wa ninu saare na fe dide, lojiji ara alagbara nla, meta ototo san wonu saare re, ti gbogbo awon eyan salo fun emi won, ina alagbara si jo saare re di eru.
Bi D Lawerence, se se esin aworo kehin aiye re niyen. Gbogbo awon eniti won ba ti nlo iwe Six and Seven Books Of Moses, won ma sesin kehin aiye won ni. Nitori Mose ko ni o ko iwe na, Awon eniti o ko iwe naa, won ko lati tako iwe mimo ni.
Mo danu duro nihin .
Bi O Ba Gbadun Onka Yi, Fi Ife Han Si Mi Nipa, Fi Follow Mi Flame of Fire and Word Fellowship
2 Minute Read With Prophet Segun David.