27/07/2026
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Naijiria àti Oke Okun
OMI IYE NAA, (January- December, 2026)
Ọjọ
Aiku (Sunday),:July 26, 2026.
ÀKÒRÍ:
ADURA GETSEMANI
AKỌSORI:
O si tún pada lọ li ẹrinkeji, o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi ago yi kò ba le ré mi kọja bikoṣepe mo mu u, ifẹ tirẹ ni ki a ṣe (Matiu 26:42).
KA:
Matiu 26:36-44
[36]. Nigbana ni Jesu bá wọn wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane, o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi nigbati mo ba lọ igbadura lọhúnyi.
[37]. O si mu Peteru ati awọn ọmọ Sebede mejeji pẹlu rẹ̀, o si bẹ̀rẹ si banujẹ, o si bẹ̀rẹ si rẹ̀wẹ̀sì.
[38]. Nigbana li o wi fun wọn pe, Ọkàn mi bajẹ gidigidi t**i de ikú: ẹ duro nihinyi, ki ẹ si mã ba mi sọ́na.
[39]. O si lọ siwaju diẹ, o si dojubolẹ o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi o ba le ṣe, jẹ ki ago yi ki o kọja kuro lori mi, ṣugbọn kì í ṣe bi emi ti nfẹ, bikoṣe bi iwọ ti fẹ.
[40]. O si tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o bá wọn, nwọn nsùn, o si wi fun Peteru pe, Kinla, ẹnyin ko le bá mi ṣọ́na ni wakati kan?
[41]. Ẹ mã ṣọna, ki ẹ si mã gbadura, ki ẹnyin ki o má ba bọ sinu idẹwò: lõtọ li ẹmi nfẹ ṣugbọn o ṣe alailera fun ara.
[42]. O si tún pada lọ li ẹrinkeji, o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi ago yi kò ba le ré mi kọja bikoṣepe mo mu u, ifẹ tirẹ ni ki a ṣe.
[43]. O si wá, o si tun bá wọn, nwọn nsùn: nitoriti oju wọn kun fun orun.
[44]. O si fi wọn silẹ, o si tún pada lọ o si gbadura li ẹrinkẹta, o nsọ ọ̀rọ kanna.
ITUPALẸ:
Adura Getsemane jẹ irúfẹ adura 'ipòrúùrù ọkan. Jesu wi pe, ọkan mi bajẹ gidigidi, títi dé ikú. O jẹ adura ti Jesu ti sọ awọn ọrọ kan náà ni igba mẹta (ẹsẹ 39,42,44). O jẹ irúfẹ adura ti kò sí èsi kan pàtó lati ọdọ Ọlọrun wá. Ni irúfẹ akoko bẹẹ, yóò dà bi ẹni pé ọrun ti ti. O jẹ akoko ti o nilo awọn eniyan lati gbadura pẹlu rẹ, tabi gbadura fún ọ. Ni irúfẹ akoko bẹẹ o le ni awọn eniyan ni ayika rẹ, ṣugbọn wọn lè ma ba ọ sọna tabi gbe