05/07/2026
BIBA OLORUN PADE LOJOOJUMO 2026
OSE KEJI-DIN-LOGBON: JULY 12, 2026. SIMONI PETERU, LATI IPO AILERA SI IPO OKUN. Maaku 8:27-29; Luku 22:31-34; Johanu 18:25-27; 21:15-17.
ESE LATI RANTI: O si wi fun un nigba keta pe, Simoni omo Jona, iwọ feran mi bi? Inu Peteru baje, nitori O wi fun un nigba eketa pe, iwo feran mi bi? O si wi fun un pc, Oluwa, Iwo mo ohun gbogbo; Iwo mo pe, mo feran Re. Jesu wi fun un pe, Maa bo awọn agutan Mi. Johanu 12:17.
JULY 6 MONDAY, 2026
A KUN UN PĘLU EMI IGBOYA
Bibeli Kika: Ise Awọn Aposteli 2:14-21
Sugbon Peteru dide pelu awọn mokanla iyoku, o gbe ohun re soke, o si wi fun won gbangba pe... Ise Awọn Aposteli 2:14a
YBH153: Wa Emi Re 'Daba Orun.
KBJL: Owe 21-23
Onkowe ni, Wayne Grudem so ninu iwe re ti o pe akole re ni "Systematic Theology" pe, "okan lara awọn apola oro ti won saaba maa n lo julo ninu Majemu Tuntun ni kun fun Ẹmi Mimo." O wi pe "Ise Emi Mimo ni lati se afihan iwalaaye Olorun lekunrere ninu aye, paapaa julo ninu ijo Olorun. On ro Ijo ni agbara, on sọ ọ di mimo, o n se afihan, o sin so ijo di okan.
Ninu abala eko ti oni, Peteru, eni ti o ti se Kristi ni igba meta dide pelu igboya lati ba opo eniyan soro. Aşiri to wa leyin igboya Peteru ko seyin iriri Pentikosti, eyi ti o fi idi ileri Jesu Kristi fun awon omo-eyin Re gege bi a se rii ninu Ise Awọn Aposteli 1:8 mulę pe Ẹmi Mimo yoo fun won ni agbara lati lee je eleri ni Jerusalemu, Judia ati ni Samaria ati t**i de opin ile-aye. Igboya re lati le ba opo eniyan soro se afihan ise Emi Mimo ninu aye onigbagbo.
Nje o ti gba Emi Mimo? Se O wa lenu ise ninu re? O le se nnkan nla fun Ọlọrun gege bi Peteru ati awọn ọmọ-eyin yooku. O ni lati duro, pongbę ki o si gbadura ki Emi Mimo ro o lagbara. Agbara eniyan le kuna nigbakuugba; idi niyi ti o fi gbọdọ gbekele Emi Olorun lati dari, to, pase ati lati fun ọ ni okun fun ise-iranse. Yonda ara rẹ fun Un lonii, Yoo si kuno lakotun.
•Oro Ogbon: Igboya lati se ise Olorun n ti odo Jesu Kristi nikan wa.
• Oro fun Ironu : Ta ni orisun igboya re?
• Ise Şişe: Pinnu lati duro ni iwaju Olorun lati gba Emi igboya.
• Adura: Oluwa, kun mi pelu agbara Emi Re, kin ba a le je eleri tooto Re, ki n si le dojuko idanwo akoko yii.
Gbadura fun awọn Ẹni-Ọwo wonyi, idile ati awọn ọmọ ijo Olorun: James Swam, Gonin Gora; Solomon Adedunmola A., Eko; Akpan Bassey E., AbiatiAkamkpa; Sunday Adeoye B., Cote d'Ivoire; Emmanuel Keshi, Obrikon; Yunana Bamaiyi, DumnaDutse; Enugu Sheba, Dangir; Philibus Maikeff M., Ibadan; Amos E. Fidoro, Delta; Richard Adjerhore, Delta; Gabriel I. Akinyola, Ila-Orangun; A. Lawrence Adigun, Ejigbo; Stephen Ibitoye, Temidire; Oyeniran I. Joshua, Awo; Ajayi O. Israel, Ilora; Ogungboye Olusegun, Offa; Jubril B. Yahya, Auchi.
Olorun alaafia, şe ohun ti yoo dara loju Rę ninu mi
EBE ADURA FUN OȘU JULY: Baba, fun awọn aladari Ajo-Nla wa ni iran ti o ye kooro fun ise iranse ojo iwaju (Owe 29:18).