04/08/2019
*ISE IRANSE ISOTELE LATI ENU OLUSO AGUTAN J. A. OLABIYI NINU IPEJOPO MIMO TI AYIKA LAWNA IKETALELOHOJI IRU RE, ISIN IPEJOPO MIMO TI OJO OLUWA (OJO KERIN, OSU KEJO, EGBAA ODUN O LE MOKANDINLOGUN)*
E gbo ohun mi, eyin omo igbala ni Oluwa wi, inu mi din lati tun ri yin ni iwaju mi ni ODUN yii gege bi mo ti we ileri ni Oluwa wi. Awon ohun nla ni mo ti se ninu aye yin lati lee je ki e wa nihin yii lonii. Mo gba opo sile kuro lowo iku ojiji ni Oluwa wi, mo gba opo sile kuro ni owo agbara okunkun ni Oluwa wi., nibi ti ota ti wipe ko si ona emi la ona fun yin ni Oluwa wi, emi ti my ki opo ki o la okin pupa koja ni ibi ti awon ota won ti segbe ni Oluwa wi, ete buburu ti ota buburu yin ni lati parun ni mo so dasan ni Oluwa wi, eyin je ajigbese niwaju mi lati yin mi lati lati yo bi eyin ba mo awon ohun ti mo ti se fun yin ni Oluwa wi. Emi n fe ki eyin ki o fi emi imoore han nitori oore mi ati itoju baba si yin ni odun yii ni Oluwa wi, e ko orin si mi lati inu okan yin wa, e jo ki e si mu ore ti o dara wa nitori awon ohun ti emi ti se fun yin ni Oluwa wi.
E gbo ohun mi ni Oluwa wi, ipejopo mimo ti odun yii je ipejopo mimo ti oju rere, o je ipejopo mimo ti aanu ni Oluwa wi. Emi yoo daa lu gbogbo yin, emi aanu, bee si ni eyin yoo si maa se aanu fun ara yin lati ori oke yii lo ni Oluwa wi.
Eyi si ni idi ti mo fi fun yin ni koko yii fun ti odun yii ni Oluwa wi, emi yoo ran Ijoba mi sokale si gbogbo yin, bee si ni gbogbo yin pata e o maa se ife mi ni Oluwa wi. E nilo ijoba mi ninu aye yin/3x, ijoba mi yoo si de ni Oluwa wi. Ki ni eyin yoo wi bi mo ba so wipe eyin n kigbe ki ijoba mi de pelu enu yin sugbon kii se lati inu okan yin nitori iwa ati ise yin ni Oluwa wi. Bi emi ba wipe ijiya yoo wa fun awon to n se mi, ta ni yoo bo ninu re laarin yin, ye ara re wo, ninu ile, ye ara re wo, ninu idokowo yin, e ye ara yin wo, ni adugbo ti e n gbe, e ye ara yin wo, ninu ise isin yin si mi/3x, e ye ara yin wo.
A ko ha ti ko wipe awon ti a n se amona won lati owo emi mimo wa, awon ni omo Olorun, eyin ha kun fun emi mimo bi? Nibo ni e wa ni Oluwa wi, emi ni ise nla lati se laarin yin ni odun yii ninu ikorajopo yii, awon ti o wa ninu igbekun ti ara tabi ti emi, emi se tan lati tu won sile. Kii se eyi nikan, emi se tan lati ran emi mi pelu agbara ati ase lati daabo bo yin kuro ninu ewu eyi ti o n be niwaju ni Oluwa wi, idi niyi ti e fi nilo ijoba mi ki ife mi ki o lee seese ninu aye yin.
E o fun won ni iseju die, je ki olukuluku ki o maa pariwo pe, ki ijoba re de, ife tire ni ki e se, je ki won ki o gbe owo le aya won ki won ki o si maa wipe je ki ijoba re de, ife tire ni ki a se/3x, ijoba mi yoo de/2x bee si ni ati se ife mi yoo si rorun fun won ni Oluwa wi. Ijoba mi yoo de, ife le o si maa se, eyin yoo ke pe mi, ki e to ke pe mi, emi yoo ma dahun. Eyin yoo maa wa ninu mi, a o si jo wa ni idapo, bee si ni yoo si dara fun yin, ijoba mi yoo de, yoo de, ijoba mi ti de si orile ede yii/3x, ife mi ni a o si se ni orile ede yii, ife mi ni a o tesiwaju lati maa se ni orile ede yii.
Eni ibukun ni yin, e ti di eni ibukun/3x oruko mi ni Jehovah, bee si ni emi ti bukun fun gbogbo yin ni Oluwa Olorun awon omo ogun wi.