21/09/2024
E WA OLUWA NIGBATI E LE RI I
"Ẹ wá Oluwa nigbati ẹ le ri i, ẹ pè e nigbati o wà nitosí. Jẹ ki enia buburu kọ̀ ona rẹ̀ silẹ, ki elẹṣẹ si kọ̀ ironu rẹ̀ silẹ: si jẹ ki o yipada si Oluwa, on o si ṣãnu fun u, ati si Ọlọrun wa, yio si fi jì li ọpọlọpọ" (Isaiah 55:6-7).
Ohun gbogbo ni akoko wa fun laye. O ni akoko ti a le wa Oluwa, ti a le ri I. Akoko kan si wa, ti eniyan le wa Oluwa, ki o ma si ri I.
A ri i ka ninu Bibeli wipe, "Nigbati Saulu si bere lọdọ Oluwa, Oluwa kò da a lohùn nipa alá, nipa Urimu tabi nipa awọn woli" (1 Sam. 28:6).
Saulu ni oba kinni ti o koko je ni Israeli. Olorun funrare ni o yan Saulu ni oba. Ni ibere ijoba re, Olorun maa n fi ara han Saulu nigbakugba ti o ba ti wa Oluwa. Sugbon nigbati Saulu bere si i se aigboran si ofin Oluwa, Oluwa naa pa a ti si apakan lati maa se ife inu ara re. Akoko ti o ye ki Saulu ronupiwada, ki o bebe fun aanu ati idariji lodo Olorun, ona bi yoo se pa Dafidi ni o n wa kiri.
Saulu ni akoko lati maa wa Dafidi kiri lati pa a, sugbon ko ni akoko lati wa Oluwa. Nigbati awon Filistini wa gbe ogun de lati ba Israeli jagun, eru, ipaya ati iwariri mu Saulu, ko si mo ohun ti yoo se mo. O gbadura si Oluwa, adura re ko gba. O to awon woli Oluwa lo, awon wolii ko ri iran fun un nitoripe akoko ti Saulu le wa Oluwa ki o si ri I ti koja.
"Saulu si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ ba mi wá obinrin kan ti o ni ẹmi abokusorọ, emi o si tọ ọ lọ, emi o si bere lọdọ re. Awọn iranṣẹ re si wi fun u pe, Wõ, obinrin kan ni Endori ti o ni ẹmi abokusorọ" (1 Sam. 28:7).
Nigbati Saulu wa Oluwa, ti ko ri I, o gba odo abokusorọ lo. Abayori re ko dara fun un rara. Odo abokusorọ ni o ti gbo ojo iku re ati iku awon omo re meta (1 Sam. 28:15-19).
Oro Olorun so wipe, "Ẹ wá Oluwa nigbati ẹ le ri i, ẹ pè e nigbati o wà nitosí. Jẹ ki enia buburu kọ̀ ona rẹ̀ silẹ, ki elẹṣẹ si kọ̀ ironu rẹ̀ silẹ: si jẹ ki o yipada si Oluwa, on o si ṣãnu fun u, ati si Ọlọrun wa, yio si fi jì li ọpọlọpọ." (Isaiah 55:6-7).
Ore, akoko ni eyi ti o le wa Oluwa ki o si ri I. Akoko ni eyi ti o le pe Oluwa nitori o wa nitosi re. Ko gbogbo ona buburu ti o ti nrin ati gbogbo iwa buburu ti o nhu sile, ki o si yipada si Olorun. Mase je ki oro re da bii ti Saulu, eniti o duro de akoko ti ko le ri Oluwa ki o to maa wa a.
Loni, opo eniyan ni ko wa Oluwa nitoripe ara tu won. O di igba ti isoro ba de ki won to maa wa Oluwa pelu pajawiri. Mase duro de ojo isoro ki o to maa wa Oluwa. Gegebii ti Saulu, iwo naa le wa Oluwa, ki o ma ri I.
Iwe Heberu 4:16 wipe, "Nitorina ẹ jẹ ki a wá si ibi itẹ ore-ọfẹ pẹlu igboiya, ki a le ri ãnu gbà, ki a si ri ore-ọfẹ lati mã rànnilọwọ ni akoko ti o wo."
Ko si bi igba ti wu ki o le koko to, bi o ba fi tokantokan wa Oluwa, yoo so igba lile di riro fun o. Orin Dafidi 34:10 so wipe: "Awọn ọmọ kiniun a ma ṣe alaini, ebi a si ma pa wọn: ṣugbọn awọn ti nwá Oluwa, kì yio ṣe alaini ohun ti o dara."
Wa Oluwa nigbati o le ri I.
Gba awon koko adura wonyii:
1. Oluwa, fun mi ni oore-ofe lati maa fi tokantokan mi wa O lati oni lo.
2. Oluwa, ran mi lowo lati fi gbogbo iwa ati ise ti ko ba ife Re mu sile lati oni lo.
3. Je ki ife lati maa se ohun ti o wu o wo inu mi lati oni lo, ni oruko Jesu.