22/07/2026
BI A SE LE KA BIBELI NI ỌNA TI A LE GBA LÓYE RẸ̀.
Ohun ti o dara gbaa ni bi ènìyàn ba dantọ lati mọ ohun ti Ọlọrun n sọ láti inú ọrọ Rẹ.
Ọ̀na ti Stefanu fi gbe iwasu ikẹhin rẹ jáde jẹ èyí ti o kún fún iná agbara ọrọ Ọlọrun, èyí ni o si fi Stefanu hàn gẹgẹ bi ẹnití o dantọ ninu ìmọ Bíbélì àti ẹnití o ye ohun ti o wa ninu Bibeli ye.
Njẹ iwọ na fẹ de iru ipele ẹmi bayi bi?
Ise A A 7:1-60 {54-56}.
Ẹnití ko bá mọ ọrọ Ọlọrun dàbí ẹnití o sọ wúrà olowo iyebiye nu.
NITORINA O NILO LATI MỌ BI O SE LE KA BIBELI NI Ọ̀NÀ TÍ YOO FI YE Ọ.
Awọn ọna ti mo fẹ mẹnu ba yi, yoo rán ọ lọwọ dáadáa láti le jẹ ki Bibeli ye ọ ki o si le gba ìmísí nípa rẹ, nigbati o ba n ka Bibeli:
1. Setan lati wa ìmọ nipa rẹ (Bíbélì):
Ẹnití o fẹ ka Bibeli ni ọna ti yoo fi mọ ìtumọ rẹ gbọdọ le san owo idiyelé rẹ, ni awọn ọna wọnyi:
- Iru ẹnibẹ gbọdọ le se tan lati na owo si rira awọn orisirisi Bíbélì ati awọn iwe ìmọ nipa alaye Bíbélì.
- Iru ẹnibẹ gbọdọ le se tan lati ra ìmọ̀ ni ọdọ àwọn ti o ni imọ ijinlẹ nínú Bíbélì, nitori akoko imusẹ àsọtẹlẹ nipa iyan ọrọ Ọlọrun ni awa yi, nitorina ọmọ Ọlọrun ti yoo ba ni ojúlówó ìmọ̀ ọrọ Bíbélì ni akoko ti a wa yi gbọdọ se tan lati fun ni ohun gbogbo ti o ba gba.
📚"Kiyesi i, ọjọ na de, li Oluwa Ọlọrun wi, emi o rán iyàn wá si ilẹ na, kì iṣe iyàn onjẹ, tabi ongbẹ fun omi, ṣugbọn iyàn gbigbọ́ ọ̀rọ Oluwa: Amosi 8:11.
📚"Ijọba ọrun si dabi iṣura ti a fi pamọ́ sinu oko, ti ọkunrin kan ri, ti o pa a mọ́; nitori ayọ̀ rẹ̀, o lọ, o si ta gbogbo ohun ti o ni, o si rà oko na" Mat 13:44.
📚"Ati pẹlu, ijọba ọrun si dabi ọkunrin oniṣowo kan, ti nwá perli ti o dara:
Nigbati o ri perli olowo iyebiye kan, o lọ, o si tà gbogbo nkan ti o ni, o si rà a Mat 13:45-46.
📚"Ofin ẹnu rẹ dara fun mi jù ẹgbẹgbẹrun wura ati fadaka lọ" Psalm 119:72.
2. Beere fún imisi Emimọ nínú àdúrà:
Ki o to bẹrẹ kika Bibeli gbàdúrà kí Ọlọ́run fún ọ ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti lóye awọn ẹsẹ ti o fẹ ka.
"Là mi ni oju, ki emi ki o le ma wò ohun iyanu wọnni lati inu ofin rẹ.
Psalm 119:18.
3. Ya akoko ijiroro rẹ sọtọ:
Ohun ti o dara julọ ti a ba fẹ ka Bibeli ni ọna ti a o fi gba' ìtumọ rẹ ni ọwọ Emi-mimo ni ki a ya akoko kika Bibeli sọtọ láàrin "àwọn akoko aniyan wa" paapa julọ fún awa ti òye nipa gbigba ìmísí ninu ọrọ Ọlọrun ko ba i ti ma ye daada.
📚"Isaaki si jade lọ ṣe àṣaro li oko li aṣalẹ ----" Gen 24:63.
4. Ka ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ:
Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹsẹ kan kí o si ri wipe o gba ìmísí itumọ lórí ẹsẹ na ki o to tun lọ si ẹsẹ miran Job 2:4.
5. Mọ awọn n kan yi:
Fún ẹnití o ye bíbélì ko i ti ma ye daada, fún ẹnití o sẹsẹ fẹ bẹrẹ lati ma ka bibeli, ma ti kánjú lọ ma ka awọn iwe wọnyi:
- Eksodu
- Numeri
- Deuteronomi
- Danieli
- Ìfihàn
- Kronika
- Ẹkun Jeremiah
- Matiu 1:1-17 ati awọn iwe miran. Nítorí awọn ọrọ ijinlẹ pọ ninu awọn iwe yi.
Fún ẹnití o ye awọn ìtumọ ẹsẹ ọrọ ko i ti ma ye daadaa. Odara púpọ ki ẹnina bẹrẹ ijiroro Bibeli kika rẹ ninu awọn iwe Bibeli wọn yi:
- Jenesisi
- Awọn ori ti o saaju ninu iwe Joshua.
- Samueli
- Esteri
- Iwe Johanu✓
ati awọn iwe miran. Awọn iwe wọnyi dara fun awọn asẹsẹ bẹrẹ tabi awọn ti ọrọ inu Bibeli ko i ti ma ye daadaa nitori wọn jẹ awọn iwe:
- Itan.
- Ìsẹlẹ.
- Ìtumọ awọn ọrọ inu wọn lọ ni geerere.
6. Wo àyíká ẹsẹ Bibeli ti o fẹ ka náà (Context):
Má ṣe yọ ẹsẹ kan kúrò ní àyíká rẹ. Ka ẹsẹ ti o ṣáájú àti ẹsẹ ti o tẹ̀lé e.
7. Fi Bíbélì sàlàyé Bíbélì: Fi àwọn ẹsẹ míì tó sọ nípa kókó kan wé ara wọn
2Tim 3:16-17.
8. Mọ irú ìwé tí o ń ka:
Diẹ̀ jẹ́ ìtàn, diẹ̀ jẹ́ orin, owe, asọtẹ́lẹ̀, lẹ́tà, tàbí ìran. Ìyẹn máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ ìtumọ wọn dáadáa.
9. Se àkọsílẹ̀:
- Kọ ohun tí o kọ́ silẹ.
- Kọ àwọn ohun ti ko ye ọ silẹ, ki o si beere lọwọ àwọn òbí tabi awọn alagbatọ rẹ ninu Oluwa.
10. Lo àwọn ìtọ́kasí Bíbélì: Se awárí àwọn ẹsẹ tó jọra (cross references) láti ní òye tó jinlẹ̀ síi. Fun apẹrẹ
Ni atetekose Jenesisi 1:1 yatọ si' ni atetekose
Johanu 1:1.
11. Lo Bíbélì ti ìtumọ ede rẹ rọ run:
Bí o bá lè se é, fi àwọn ìtumọ̀ Bíbélì méjì tàbí mẹ́ta wé ara wọn láti lóye àwọn ọ̀rọ̀ tó nira nítorí ani ọpọ awọn orisirisi ìtumọ (version) Bíbélì bi:
- KJV (King James Version)
- NKJV (New King James Version)
- NIV (New International Version)
- ESV (English Standard Version)
- NASB (New American Standard Bible)
- CSB (Christian Standard Bible)
- NLT (New Living Translation)
- GNT/GNB (Good News Translation/Bible)
- RSV (Revised Standard Version)
- NRSV (New Revised Standard Version)
- AMP (Amplified Bible)
- The Message (MSG)
- Good news.
12. Gbé ohun tí o kà sí ìṣe: Ìmọ̀ Bíbélì máa jinlẹ̀ síi nígbà tí a bá ń gbé aye wa gẹ́gẹ́ bí ìlànà àwọn ohun ti a ka. "Ṣugbọn ki ẹ jẹ oluṣe ọ̀rọ na, ki o má si ṣe olugbọ́ nikan, ki ẹ mã tàn ara nyin jẹ" Jakọbu 1:22.
13. Máa ka Bíbélì ní gbogbo ọjọ́: Ìfaradà àti ìtẹ̀síwájú ni ń mú ìmọ̀ jinlẹ̀.
"Iwé ofin yi kò gbọdọ kuro li ẹnu rẹ, ṣugbọn iwọ o ma ṣe àṣaro ninu rẹ̀ li ọsán ati li oru, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ sinu rẹ̀: nitori nigbana ni iwọ o ṣe ọ̀na rẹ ni rere, nigbana ni yio si dara fun ọ"
Joṣua 1:8.
14. Béèrè lọwọ ara rẹ nígbà gbogbo ti o ba n ka Bibeli wipe:
- Ta ni ó kọ ọ iwe yi?
- Ta ni a kọ ọ sí?
- Kí ni ìdí tí a fi kọ ọ?
- Kí ni ẹsẹ náà túmọ̀ sí?
- Báwo ni mo ṣe lè fi sí ìṣe lónìí?
-----------------------------------------------------------------------
✍️✍️✍️✍️✍️✍️✍️✍️✍️✍️✍️✍️✍️
Efi comment yin s'ọwọ si abẹ ẹkọ yi fun ibeere, tabi ọrọ ìmọ riri.
-----------------------------------------------------------------------
Anfani wa fun yin lati darapọ̀ mọ WhatsApp group ile ise-iranse yi nibiti ẹ o ti ma gba awọn audio ẹkọ ti o wa lati ile ise-iranse yi ni ọfẹ.
Edarapọ pẹlu WhatsApp link 🔗 yi.
👇👇👇
https://chat.whatsapp.com/F7TSdwr1fKh1wKO8HXjIKw
-----------------------------------------------------------------------
+2348124247703
Olasunkanmi
Alabi Jesumbo.