06/04/2026
ERI AWON APOSTELI
IJO APOSTELI TI KRISTI
Tuesday 7 April, 2026
AKORI:
ABRAHAMU SI FI GBOGBO OHUN TI O NI FUN ISAAKI
Akosori:
Abrahamu si fi gbogbo ohun ti o ni fun Isaaki. Genesisi 25:5
Ibi Kika: Genesisi 25:1-11.
ALAYE LEKUNRERE:
Awon onka Bibeli toni ni ohun pupo lati ko lati odo Abrahamu ki o to ku. O ni anfani lati se eto ile re ni deede ki o to jowo emi re lowo. Iwe mimo koo sile wipe, Abrahamu si fi gbogbo ohun ti o ni fun Isaaki. Sugbon fun awon omo ale ti Abrahamu ni, o fun won ni ebun, o si ran won kuro ni odo Isaaki omo re nigba ti o wa laaye, si ila oorun, de opin ile ila oorun (ese 5, 6). Abrahamu se eeto ti o kun fun ogbon lati dena owu jije ati wahala laarin awon omo re. Idi pataki ni wipe ki won le gbe ni awon ilẹ miiran, ki won ma baa ja fun ipinle Isaaki ninu eto Olorun fun un ati irandiran re lati ni ilẹ Kenaani gẹgẹ bi ileri ninu majemo Abrahamu (Gen 13:14-17; 15:18-21; 17:8). O je asa lati maa fi gbogbo ohun ini fun akobi omokunrin ti o je ti iyawo akọkọ. Awon omo ale kii jogun eni ayafi nigba ti ko ba si omo iyawo ti a fe nipa ofin, o si gbodo je pelu ifowosi iyawo naa. Ofin akoko naa gba won laaye lati gba awon ebun pataki kan lati odo baba won. Pipin awon omo Abrahamu niya kuro lodo ara won wa ni isokan pelu ife Olorun nipa pe ki orile-ede naa ti a yan o le pin ara re niya kuro lodo gbogbo awon iran miiran ki Mesaya le wa gẹgẹ bi a ti so asotele Re. Olukawe tooto, iru eeto wo ni o n se fun awon omo re ati aya re saaju iku? Fun o lati sun un re, ma se jẹ alafara nipa kikuna lati se eeto ile re daadaa ki o si se ohun ti o yẹ nigba ti o si ni anfaani wura yii. Ma se so idile re sinu ogun leyin iku re lori ohun gbogbo ti o ti sise fun. Dawo duro ninu fifi nnkan dola, ṣe e bayi: seeto ogun sile.
Adura:
Gbadura fun ogbon lati ṣe eeto ti o mu ogbon dani fun idile re.