26/08/2026
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Naijiria àti Oke Okun
OMI IYE NAA, (January- December, 2026)
Ọjọru (Wednesday), August 26, 2026.
ÀKÒRÍ:
TITẸSIWAJU SII PẸLU JESU (1)
AKỌSORI:
Ṣugbọn nigbati Jesu gbọ́, o da a li ohùn, wipe, Má bẹ̀ru: gbagbọ́ nikan ṣa, a o si mu u larada (Luku 8:50).
KA:
Luku 8:49-56
[49]. Bi o si ti nsọ̀rọ li ẹnu, ẹnikan ti ile olori sinagogu wá, o wi fun u pe, Ọmọbinrin rẹ kú; má yọ olukọni lẹnu mọ.
[50]. Ṣugbọn nigbati Jesu gbọ́, o da a li ohùn, wipe, Má bẹ̀ru: gbagbọ́ nikan ṣa, a o si mu u larada.
[51]. Nigbati Jesu si wọ̀ ile, kò jẹ ki ẹnikẹni wọle, bikoṣe Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, ati baba on iya ọmọbinrin na.
[52]. Gbogbo nwọn si sọkun, nwọn pohùnrere ẹkún rẹ̀: o si wi fun wọn pe, Ẹ má sọkun mọ́; kò kú, sisùn li o sùn.
[53]. Nwọn si fi i ṣẹ̀fẹ, nwọn sa mọ̀ pe o kú.
[54]. Nigbati o si sé gbogbo wọn mọ́ ode, o mu u li ọwọ́, o si wipe, Ọmọbinrin, dide.
[55]. Ẹmí rẹ̀ si pada bọ̀, o si dide lọgan: o ni ki nwọn ki o fun u li onjẹ.
[56]. Ẹnu si yà awọn õbi rẹ̀: ṣugbọn o kilọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe wi fun ẹnikan li ohun ti a ṣe.
ITUPALẸ:
Jesu sábà maa n ba awọn ọmọ ẹyin Rẹ sọrọ, ti o duro lori ipele igbagbọ wọn ati bi wọn ṣe dagba tojuubọ ninu ẹmi si, gẹgẹ bi a ṣe ri ninu awọn apẹẹrẹ nibi ti yóò ti sọ fun awọn ọmọ ẹyin mẹsàn -an lati duro lẹyin nigba ti Oun yóò si tẹsiwaju pẹlu awọn mẹta. Ninu ibi kika ti òni, Jairu pe Jesu lati wá wo ọmọde binrin rẹ ti o n kú lọ sản, Jesu gbà, Ó si bẹrẹ irinajo lọ si ilé Jairu. Ṣugbọn ọ̀pọ̀ èrò yi I ká, eyi ti o mu ki irin Rẹ ki o falẹ. Nigba ti wọn de ilé Jairu, Jesu gba awọn perete láàyè lati tẹsiwaju pẹlu Rẹ. Awọn mẹsan-an ti o kù n kọ?
Ninu irin ajo Kristẹni wa, ọpọlọpọ ni o n tẹlé Jesu, ṣugbọn awọn kan kò ni ireti kan pató. Wọn kò tii ni iriri iṣẹ ami Ọlọrun ti kò ni abùlá ojukooju: wọn kan n gbọ nipa wọn ni. Awọn ẹlomiran dà bi awọn èro iwòran ni ilé Jairù, ti wọn n ṣe iyemeji nipa iṣẹ iyanu ti wọn si n yára lati yọ sùti ètè sí ijakulẹ. Ohun ibanujẹ ni pe ọpọ awọn onigbagbọ a maá dúró láảrin awọn èro, ti wọn si n padanu awọn ijinlẹ ibukún igbagbọ.
Iriri wa pẹlu Ọlọrun dá lóri Igbagbọ wa ati bi a ṣe dàgba tojuubọ si. Lati lè ri awọn iṣẹ àmi ati iyanu, a gbọdọ máá dàgbà ni ojoojumọ nipa bíbá Kristi rin timọtimọ. Awọn iṣẹ Rẹ tẹsiwaju ati pé titẹsiwaju pẹlu Rẹ a máa mú awọn iriri agbara Rẹ wá lọna tí o yatọ. Njẹ o n fojusọna fún iṣẹ àmi Ọlọrun bi? Gbé igbésẹ̀ igbagbọ ki o si tẹsiwaju pẹlu Jesu
Awọn koko Adura
1. Olúwa, fi kún igbagbọ mi ki O si ràn mi lọwọ lati tẹsiwaju pẹlu Rẹ ni ojoojumọ.
2. Baba, mu gbogbo idiwọ ti o n fa mi sẹyin ninu irin mi pẹlu Rẹ kuro.
3. Gbàdúrà fún àfikún agbara ati iwàláàyè Ọlọrun ní CAC Ẹkun Gbooro Anosike, ninu aye baba wa, Alabojuto Ẹkun naa, awọn oloye miiran ati awọn ọmọ ijọ ni oniruuru ipele, ni orukọ Jesu.
Orin Ti A Dabaa Fun Oni:
C.A.CGHB: 627
OKOOLELẸGBẸTA O LE MEJE
8 8 8 D
Nitoriti a fi ipinlẹ rẹ sọlẹ lori apata.
Mat. 7:25
1. Igbagbo mi duro l'ori,
Eje at' ododo Jesu,
Nko je gbekele ohun kan,
Leyin oruko nla Jesu.
Mo duro le Kristi Apata,
Ile miran, iyanrin ni.
2. B'ire-ije mi tile gun,
Or'-ofe Re ko yi pada;
B'o ti wu ki iji na le to
Idakoro mi ko niye.
3. Majemu, ati eje Re
L'em'o ro mo, bi 'kun mi de;
'Gbati ko s'atileyin mo
On je ireti nla fun mi.
4. 'Gbat'ipe 'keyin ba si dun,
A! mba le wa ninu Jesu;
Ki nwo ododo Re nikan
Ki nduro niwaju ite.
Amin.
Afikun Ibi kika Fun Oni:
Jeremáyà 15 - 17