Ifẹ ni Ọlọrun

Ifẹ ni Ọlọrun Awọn arakunrin ati arabinrin ninu Kristi. CBM Christadelphians Yoruba

28/03/2026

Help needed to complete CBM Media video booklet in Yoruba "Do people go to heaven when they die?" We have made the video booklet, but do not yet have a proper soundtrack. This test version is made with an English lady reading the Yoruba phonetically which sounds very unnatural. We are looking for a Yoruba speaker (man or woman) who can record a 7 minute audio file mp3 that we will add to the Yoruba basic video mp4. If you cannot help then please share to someone who can. Thank you.

Heberu 5:7 Ní ìgbà ọjọ́ Jesu nínú ayé, ó fi ìkérora rara àti omijé gbàdúrà, tí ó sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó lè gbà á sílẹ...
22/02/2025

Heberu 5:7 Ní ìgbà ọjọ́ Jesu nínú ayé, ó fi ìkérora rara àti omijé gbàdúrà, tí ó sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, a sì gbóhùn rẹ̀ nítorí ó ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ̀. 8 Bí òun tilẹ̀ ń ṣe Ọmọ Ọlọ́run, síbẹ̀ ó kọ́ ìgbọ́ran nípa ohun tí ó jìyà rẹ̀; 9 Bí a sì ti sọ ọ di pípé, o wa di orísun ìgbàlà àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ tirẹ̀: 10 Tí a yàn ní olórí àlùfáà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ní ipasẹ̀ Melkisedeki.

"Majẹmu" - Lumo Majẹmu Lailai Film "The Covenant" - Lumo Old Testament Film – Yoruba (1 hour 35 minutes)
09/08/2024

"Majẹmu" - Lumo Majẹmu Lailai Film

"The Covenant" - Lumo Old Testament Film – Yoruba (1 hour 35 minutes)

SEKARIAH 9:9 Ọba sioni ń bọ̀9 Kún fún ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni,hó ìhó ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu:Wo ọba rẹ ń bọ̀ wá...
25/04/2024

SEKARIAH 9:9 Ọba sioni ń bọ̀

9 Kún fún ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni,
hó ìhó ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu:
Wo ọba rẹ ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ:
òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà;
ó ní ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

Àsọtẹ́lẹ̀ Sekaráyà yìí nímùúṣẹ nínú Mátíù 21:5 àti Ìhìn Rere Jòhánù 12:15 .

9 Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni!
Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu!
Wò ó! Ọba yín ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín;
ajagun-ṣẹ́gun ni,
sibẹsibẹ ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
kódà, ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni ó gùn

Jésù ṣàlàyé pé: “Àwọn ọmọ Ọlọ́run” wọ̀nyí jẹ́ ènìyàn. Awon angeli ki i se igbeyawo. Wo Mátíù 22:30 àti Lúùkù 20:36 . Awo...
31/05/2023

Jésù ṣàlàyé pé: “Àwọn ọmọ Ọlọ́run” wọ̀nyí jẹ́ ènìyàn. Awon angeli ki i se igbeyawo. Wo Mátíù 22:30 àti Lúùkù 20:36 . Awon angeli ki nse ese. Wo Heberu 1:14 ni o tọ

GẸN 6 Ìwà Burúkú Eniyan

6:1 O si ṣe nigbati enia bẹ̀rẹ si irẹ̀ lori ilẹ, ti a si bí ọmọbinrin fun wọn, 2 Ni awọn ọmọ Ọlọrun ri awọn ọmọbinrin enia pe, nwọn lẹwà; nwọn fẹ́ aya fun ara wọn ninu gbogbo awọn ti nwọn yàn. 3 OLUWA si wipe, Ẹmi mi ki yio fi igba-gbogbo ba enia jà, ẹran-ara sa li on pẹlu: ọjọ́ rẹ̀ yio si jẹ ọgọfa ọdún. 4 Awọn òmirán wà li aiye li ọjọ́ wọnni; ati lẹhin eyini pẹlu, nigbati awọn ọmọ Ọlọrun wọle tọ̀ awọn ọmọbinrin enia lọ, ti nwọn si bí ọmọ fun wọn, awọn na li o di akọni ti o wà nigbãni, awọn ọkunrin olokikí. 5 Ọlọrun si ri pe ìwabuburu enia di pipọ̀ li aiye, ati pe gbogbo ìro ọkàn rẹ̀ kìki ibi ni lojojumọ.
6 Inu OLUWA si bajẹ nitori ti o dá enia si aiye, o si dùn u de ọkàn rẹ̀.
7 OLUWA si wipe, Emi o pa enia ti mo ti dá run kuro li ori ilẹ; ati enia, ati ẹranko, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju-ọrun; nitori inu mi bajẹ ti mo ti dá wọn. 8 Ṣugbọn Noa ri ojurere loju OLUWA.

After breaking of bread at Lagos Christadelphian Meeting Hall. Bible study weekend.
29/11/2022

After breaking of bread at Lagos Christadelphian Meeting Hall. Bible study weekend.

Christadelphian Meeting Hall, Lagos Nigeria IṢE APO 20:17-38  Paulu Bá Àwọn Alàgbà Efesu Sọ̀rọ̀17 Ati lati Miletu o ranṣ...
04/09/2022

Christadelphian Meeting Hall, Lagos Nigeria

IṢE APO 20:17-38 Paulu Bá Àwọn Alàgbà Efesu Sọ̀rọ̀

17 Ati lati Miletu o ranṣẹ si Efesu, lati pè awọn alàgba ijọ wá sọdọ rẹ̀. 18 Nigbati nwọn si de ọdọ rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹnyin tikaranyin mọ̀, lati ọjọ ikini ti mo ti de Asia, bi emi ti ba nyin gbé, ni gbogbo akoko na, 19 Bi mo ti nfi ìrẹlẹ ọkàn gbogbo sìn Oluwa, ati omije pipọ, pẹlu idanwò, ti o bá mi, nipa ìdena awọn Ju: 20 Bi emi kò ti fà sẹhin lati sọ ohunkohun ti o ṣ'anfani fun nyin, ati lati mã kọ́ nyin ni gbangba ati lati ile de ile, 21 Ti mo nsọ fun awọn Ju, ati fun awọn Hellene pẹlu, ti ironupiwada sipa Ọlọrun, ati ti igbagbọ́ sipa Jesu Kristi Oluwa wa. 22 Njẹ nisisiyi, wo o, ọkàn mi nfà si ati lọ si Jerusalemu, laimọ̀ ohun ti yio bá mi nibẹ̀: 23 Bikoṣe bi Ẹmí Mimọ́ ti nsọ ni ilu gbogbo pe, ìde on ìya mbẹ fun mi. 24 Ṣugbọn emi kò kà ẹmi mi si nkan rara bi ohun ti o ṣọwọn fun mi, ki emi ki o ba le fi ayọ̀ pari ire-ije mi ati iṣẹ-iranṣẹ ti mo ti gbà lọdọ Jesu Oluwa, lati mã ròhin ihinrere ore-ọfẹ Ọlọrun. 25 Njẹ nisisiyi, wo o, emi mọ̀ pe gbogbo nyin, lãrin ẹniti emi ti nkiri wãsu ijọba Ọlọrun, kì yio ri oju mi mọ́. 26 Nitorina mo pè nyin ṣe ẹlẹri loni yi pe, ọrùn mi mọ́ kuro ninu ẹ̀jẹ enia gbogbo. 27 Nitoriti emi kò fà sẹhin lati sọ gbogbo ipinnu Ọlọrun fun nyin. 28 Ẹ kiyesara nyin, ati si gbogbo agbo ti Ẹmí Mimọ́ fi nyin ṣe alabojuto rẹ̀, lati mã tọju ijọ Ọlọrun, ti o ti fi ẹ̀jẹ ara rẹ̀ rà. 29 Nitoriti emi mọ̀ pe, lẹhin lilọ mi, ikõkò buburu yio wọ̀ ãrin nyin, li aidá agbo si. 30 Ati larin ẹnyin tikaranyin li awọn enia yio dide, ti nwọn o ma sọ̀rọ òdi, lati fà awọn ọmọ-ẹhin sẹhin wọn.
31 Nitorina ẹ mã ṣọra, ki ẹ si mã ranti pe, fun ọdún mẹta, emi kò dẹkun ati mã fi omije kìlọ fun olukuluku li ọsán ati li oru.
32 Njẹ nisisiyi, ará, mo fi nyin le Ọlọrun lọwọ ati ọ̀rọ ore-ọfẹ rẹ̀, ti o le gbe nyin duro, ti o si le fun nyin ni ini lãrin gbogbo awọn ti a sọ di mimọ́. 33 Emi kò ṣe ojukòkoro fadaka, tabi wura, tabi aṣọ ẹnikẹni.
34 Ẹnyin tikaranyin sá mọ̀ pe, ọwọ́ wọnyi li o ṣiṣẹ fun aini mi, ati ti awọn ti o wà pẹlu mi. 35 Ninu ohun gbogbo mo fi apẹrẹ fun nyin pe, nipa ṣiṣe iṣẹ bẹ̃, yẹ ki ẹ mã ràn awọn alailera lọwọ, ki ẹ si mã ranti ọ̀rọ Jesu Oluwa, bi on tikararẹ̀ ti wipe, Ati funni o ni ibukún jù ati gbà lọ. 36 Nigbati o si ti wi nkan wọnyi, o kunlẹ, o si ba gbogbo wọn gbadura. 37 Gbogbo wọn si sọkun gidigidi, nwọn si rọ̀ mọ́ Paulu li ọrùn, nwọn si fi ẹnu kò o li ẹnu, 38 Inu wọn si bajẹ julọ fun ọ̀rọ ti o sọ pe, nwọn kì yio ri oju on mọ́. Nwọn si sìn i lọ sinu ọkọ̀.

Are you ready for the kingdom of God? Part 1CBM video 17 minutes  (English version)
27/07/2022

Are you ready for the kingdom of God? Part 1
CBM video 17 minutes (English version)

The bibe truth about the kingdom of God

Address

Ibadan

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Ifẹ ni Ọlọrun posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Place Of Worship

Send a message to Ifẹ ni Ọlọrun:

Share

Category