Kini bibeli wi ?,What bible says?

Kini bibeli wi ?,What bible says? Ki emi ki o le mọ̀ ọ, ati agbara ajinde rẹ̀, ati alabapin ninu ìya rẹ̀, nigbati mo ba faramọ ikú rẹ̀

12/07/2026

Big shout out to my newest top fans! Abosede Adekola Adejumo

12/07/2026

Orin Dafidi 35
1 OLUWA gbogun tì awọn ti o gbogun tì mi: fi ìja fun awọn ti mba mi jà.
2 Di asà on apata mu, ki o si dide fun iranlọwọ mi.
3 Fa ọ̀kọ yọ pẹlu, ki o si dèna awọn ti nṣe inunibini si mi: wi fun ọkàn mi pe, emi ni igbala rẹ.
4 Ki nwọn ki o dãmu, ki a si tì awọn ti nwá ọkàn mi loju: ki a si mu wọn pada, ki a si dãmu awọn ti ngbiro ipalara mi.
5 Ki nwọn ki o dabi iyangbo niwaju afẹfẹ: ki angeli Oluwa ki o ma le wọn.
6 Ki ọ̀na wọn ki o ṣokunkun ki o si ma yọ́; ki angeli Oluwa ki o si ma lepa wọn.
7 Nitori pe, li ainidi ni nwọn dẹ àwọn wọn silẹ fun mi, nwọn wà iho silẹ fun ọkàn mi li ainidi.
8 Ki iparun ki o wá si ori rẹ̀ li ojiji; àwọn rẹ̀ ti o dẹ, ki o mu on tikararẹ̀: iparun na ni ki o ṣubu si.
9 Ọkàn mi yio si ma yọ̀ niti Oluwa: yio si ma yọ̀ ninu igbala rẹ̀.
10 Gbogbo egungun mi ni yio wipe, Oluwa, tali o dabi iwọ, ti ngbà talaka lọwọ awọn ti o lagbara jù u lọ, ani talaka ati alaini lọwọ ẹniti nfi ṣe ikogun?
wa gbami loose yi
àmín

29/06/2026

pray this prayer as you are going out this week
Baba mi ati Olorun mi
loose yi
fún mi ní iranlọwọ rẹ ti ma fi ro ka gbogbo ayé ọla,aanu, ọrọ ati aṣeyọri to wa ninu orukọ rẹ
àmín loruko Jesu kristi

28/06/2026

Orin Dafidi 148
1 Ẹ fi iyìn fun Oluwa, Ẹ fi iyìn fun Oluwa lati ọrun wá; ẹ fi iyìn fun u ni ibi giga.
2 Ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin angeli rẹ̀; ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin ọmọ-ogun rẹ̀.
3 Ẹ fi iyìn fun u, õrun ati oṣupa; ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin irawọ imọlẹ.
4 Ẹ fi iyìn fun u, ẹnyin ọrun awọn ọrun, ati ẹnyin omi ti mbẹ loke ọrun.
5 Jẹ ki nwọn ki o ma yìn orukọ Oluwa; nitori ti on paṣẹ, a si da wọn.
6 O si fi idi wọn mulẹ lai ati lailai; o si ti ṣe ilana kan ti kì yio kọja.
7 Ẹ yìn Oluwa lati aiye wá, ẹnyin erinmi, ati gbogbo ibu-omi;
8 Iná ati yinyin òjo-didì ati ikũku; ìji mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ;
9 Ẹnyin òke nla, ati gbogbo òke kekere; igi eleso, ati gbogbo igi Kedari;
10 Ẹranko, ati gbogbo ẹran-ọ̀sin; ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ́ ti nfò;
11 Awọn ọba aiye, ati gbogbo enia; ọmọ-alade, ati gbogbo onidajọ aiye;
12 Awọn ọdọmọkunrin ati awọn wundia, awọn arugbo enia ati awọn ọmọde;
13 Ki nwọn ki o ma yìn orukọ Oluwa; nitori orukọ rẹ̀ nikan li o li ọlá; ogo rẹ̀ bori aiye on ọrun.
14 O si gbé iwo kan soke fun awọn enia rẹ̀, iyìn fun gbogbo enia mimọ́ rẹ̀; ani awọn ọmọ Israeli, awọn enia ti o sunmọ ọdọ rẹ̀. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

Olúwa Olorun aanu Fi aanu Re ranmilowo l'ose tuntun yìíAmin
08/03/2026

Olúwa Olorun aanu
Fi aanu Re ranmilowo l'ose tuntun yìí
Amin

01/01/2026

Address

Ibadan

Telephone

+2349135689836

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Kini bibeli wi ?,What bible says? posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Shortcuts

Share