Kalimotullah islamic tv

Kalimotullah islamic tv PRAYER IS SOLUTION TO ANY PROBLEM.. I WAS BORN TO RULE THE WORLD�����������������
(2)

27/04/2026
15/04/2026
15/04/2026
15/04/2026
15/04/2026

AWỌN ADOJUKỌ TÍ O SABA MA N ṢẸLẸ SÌ ONÌRÀWỌ ÌNA
👉Igbogun ìdílé: Igbogún ìdílé jẹ orisun tàbí ìpilẹ̀ṣẹ̀ ogún fún gbogbo ogún toku tí ẹ̀dá ma ń dojukọ nínú ayé nítorí ogún ẹjẹ tàbí ogún alajọbi ni Igbogun ìdílé jẹ latara ẹṣẹ ìran èyí tí ẹ̀dá ń kó ẹsan rẹ tàbí Irawọ ẹlẹsan (karmic sign) èyí tí ẹ̀dá bá wà sì ile aye. Kò sí Irawọ tàbí ẹ̀dá ènìyàn tí kò ṣá í lé ní Igbogun ìdílé bẹ́ẹ̀ awọn onirawọ iná a má koju ogún yí lọpọlọpọ nítorí bí ikú ilé ó pani títa ó lè pa ni lọrọ wọn àti wípé asiwaju tàbí olórí lógún pupọ ń dojukọ. Orí awọn ọmọ onirawọ yí le to bẹẹ gẹ tí ó fi jẹ wípé asasi tàbí edi kí sábà rán wọn sugbọn awọn ọta inú ilé ma ń sábà mọ asiri agbara wọn, wọn a ma lo agbára ẹjẹ tàbí ogún alajọbi láti fi fà wọn lé ọta òde lọwọ èyí ni ó má ń fà Igbogun Ọta àti ogún alatako níbi gbogbo tí wọn ba de.

👉Igbogun Ọta: Ọta ilé a má ṣilẹkun fún ọta òde láti ráyè ṣíṣẹ nínú ayé awọn ọmọ onirawọ yi botilẹjẹwipe ikú ayé kí lè pa wọn sugbọn ọta má ń fì aye su pupọ nínú wọn latara wahala, ìdààmú àti iporuru ọkàn èyí tí wọn ma ń dá silẹ nínú ayé wọn láti má le jẹ ki wọn roju ráyè rí ògo Amutọrunwa wọn lo.

👉Ogún alatako: òní gbá ọla gbá bójú ọun ó bá fọ rakọrakọ ni yio ma wo, òwe yi gan-an ni òwe awọn ọmọ onirawọ iná nítorí wọn jẹ akíkanjú àti onigbiyanju tí ó má ń wá ọna àbáyọ sì ìṣòro lọ́nàkọ́nà sugbọn bí pupọ nínú wọn ṣe ń sapá láti rí ọna lọ awọn alatako kò jẹ bẹẹ tí alatako bá ti pọju fún ènìyàn láyé kò sì bí ó ṣe le jẹ alagabara to ipa irú wọn ma ń pín níkẹyìn ni.

👉Ogún ẹjọ́ tàbí ọ̀ràn: Pupọ nínú awọn ọmọ onirawọ iná jẹ ọmọ lile bẹẹ ìwà líle ọwọ wọn yí ma ń tí wọn láti hu ìwà jagidijangan tí èyí sì ma ń mú wọn tàpá sì ofin tàbí ṣẹ sì ofin ìjọba tí èyí sì ma ń ko wọn sínú ogún ẹjọ́ tàbí ọ̀ràn. Pupọ nínú àwọn ọmọ onirawọ yí ni wọn sábà ma ń rí ogún àtìmọ́lé Ọlọpa àti ogún ọgba ẹ̀wọ̀n he latara ìwà orí kíkún, agidi, ìjà, ainisuru-to àti aigbọràn ọwọ wọn.

👉Ìwà ọmọ líle: ninu awọn ipin Irawọ tí ọmọ líle pọ sì ju ipin Irawọ iná jẹ nọ́mbà one, pupọ nínú awọn ọmọ ìta tàbí agbero tí ó má ń hù ìwà jagidijangan inu ìpín Irawọ iná ni wọn ti ma ń sábà jáde wá ìdí ni wípé ẹ̀mí Wọn yí, ojú wọn da, wọn kò bìkítà, wọn kì bẹru àti wípé pupọ nínú jẹ ọdaju ènìyàn wọn kò bìkítà kí ọsan di òru láìro-tẹ́lẹ̀. Lóòótọ́ ọmọ líle lọjọ tìrẹ sugbọn awọn àgbàlagbà ma ń ye sì ìwà ọmọ líle wọn yí láti fi bá wọn lórúkọ jẹ àti láti fi dènà ogo wọn.

👉Ogún àfọwọ́fà: Bi kò bá ṣi tí ogún àfọwọ́fà awọn àgbàlagbà kí lè ráyè ṣíṣẹ nínú ayé ọmọ onirawọ iná nítorí ọmọ ogún àti sango ni wọn bẹẹ àwọn àgbàlagbà kí lè gbena woju awọn iseda méjì yí àti gbogbo nkan ti o ba jáde lára wọn sugbọn ogún àfọwọ́fà latara didẹja, titapa sì ofin, ṣíṣe nkan eewọ àti Igbogun ìdílé ma ń jẹ ki awọn òrìṣà abawaye awọn ọmọ onirawọ yí kawọrọ lórí ọrọ ayé wọn tí èyí sì ma ń jẹ ki awọn àgbàlagbà ráyè wọlé sí wọn lára nígbà miran.

👉Ogun alaillẹni- kan: Pupọ nínú àwọn ọmọ onirawọ iná kí sábà ni Olubadamọran àti alafọrọlọ nítorí wípé wọn kì sábà ni alajọṣe ọlọjọ pipẹ latara ìwà ọwọ wọn, pupọ nínú wọn kì n gbá ìmọran tàbí ikilọ, wọn kọnra, wọn fẹran kí àṣẹ tí wọn nìkan ma múlẹ̀ kódà nínú ìgbéyàwó tí èyí sì ma ń jẹ ki ìgbéyàwó pupọ nínú wọn tuka laipẹ ọjọ, ní ibi ìṣẹ tí wọn ba jẹ olórí awọn ọmọ ẹ̀yìn kí gba ti wọn kódà awọn ti wọn jọ jẹ àkẹgbẹ lẹ́nu ìṣẹ gan-an pápá ma ń dìtẹ̀ wọn latara ìwà òtítọ́ ọwọ wọn bẹ́ẹ̀ gbogbo wa la mọ pe olóòótọ́ kí lẹni botilẹjẹwipe awọn ọmọ onirawọ yi fẹran kí wọn ma fi ọwọ líle mú gbogbo nkan tí èyí sì ma ń saba mu ìnira dání fún ẹnikéji wọn.

👉Ori: Ipin irawo Ina jẹ ọkan ninu awọn ipin Irawọ tí o ní orí lọwọ gidigan kódà orí wọn ni agbara wọn, orí a má ja fún wọn lọpọlọpọ a sì ma ṣẹgun fún wọn níbi gbogbo sugbọn ti orí yí bá ti ṣíṣẹ títí tiko rí oúnjẹ tí yio fún ní okun miran yio bẹ̀rẹ̀ si ni rẹwẹsi bẹẹ bí irẹwẹsi bá ti dé bá orí yio di alailagbara bí orí bá sì ti di alailagbara yio bẹ̀rẹ̀ si ni tako olori tabi ki o má gbabọde fún olórí ìdí nìyí tí onirawọ iná fi nílò láti má bọ orí wọn lorekore bibẹ-kọ orí yio ma tako wọn.

👉Ogun Àìsàn ara: latara ìwà Akinkanju, ijalamba, ìtẹramọṣẹ àti aile fún ara ní ìsinmi botitọ àti botiyẹ nígbà ewe tàbí ìgbà ọdọ, ogún àìsàn ara bíi àìsàn ẹfọri, aisan oju, àìsàn ẹjẹ rírú àti àìsàn rọparọsẹ ma ń sábà dá awọn ọmọ onirawọ yí láàmú. Yàtọ̀sí èyí, àìsàn ẹfọri jẹ àìsàn Adamọ won...

13/04/2026

ONAA BAYO KAN SOSO TI A LE GBA LATI MA RI ALANU LOJOJUMO NIYI OO,,LO DAN WO AWON AJO TON LO DURO LASIKO YI,,ASIRI ELEYI GANGAN NI KO LO GBIYANJU NISIYI LARIN OJO META,AWA GAN MA MOPE ISEJU ISE LO: Eto ise aanu,,, ti eniyan fin ri aanu gba lona gbogbo,,, Lora fanta kan,, orogbo kan,, omunu ewe ewuro tiko iti gbo ,,, Toba di ni ale ti o fe sun fi orogbo eyokan sinu ewuro eyokan , gbadura bi o sefe si ki oje kio mu fanta yii Le Lori,,, sadura bi o sefe,,,
ti o ba fe ko sise fun o koko coment ko de share re tori fun afani awon elomi na, , kosi bi ogun se le ma ja eniyen to,to ba coment to de share re.

Address

Lagos

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Kalimotullah islamic tv posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Place Of Worship

Send a message to Kalimotullah islamic tv:

Share