17/11/2021
*IJO APOSTELI TI KRISTI L'AGBAYE.*
*OMI IYE NAA*
*OJORU (WEDNESDAY), NOVEMBER 17, 2021.*
*AWON OHUNKOHUN TI O BA JE ODODO.*
*Ka: Filipi 4:8-9*
*AKOSORI: Ki a ma rii ki Olorun je olooto, ati olukuluku eniyan je eke; gege bi a ti ko o fe, ki a le da o lare ninu oro re, sugbon ki iwo le segun nigba ti Iwo ba wa si idajo (Romu 3:4).*
*ITUPALE*
'So otito ki oju si ti esu' je asa ti o gbajumo nigba ti a ba fe koju ija si etan ati iro. O rorun fun iro lati wa fun igba pipe, sugbon otito yoo bori re ni ape. Aye kun fun oniruuru ero ijinle, iro, awon itan iran ni orisirisii, sugbon Olorun nikan ni o je otito, Oun si ni Otito. Lati igba isubu eniyan, nigba ti o subu kuro ti a si ba iri Olorun ninu re je, eniyan ko ri bakan naa mo O se ni laanu. O ti yato si Eledaa re Mimo ati pipe. Ero buburu, iwa buburu, etan ati oniruuru iwa ati ise aiwa-bi-Olorun ni o wa je iwa eda ti o padanu yii. Sibe, Olorun mimo ati olododo, ti O pe nitooto, ko so ireti nu lori eniyan.
Nipase Omo Re, Jesu Kristi, O si tun n wa eniyan ri lati mu u pada sinu ibasepo ti o pe pelu Re. Enikeni ti o ba se amulo ebun irapada yii ni a ko da lebi sugbon a wo o ni ododo ati otito ti Olorun *(I Korinti 3:19,21)*.
Otito tumo si iwa pipe (didi iwa omoluabi mu) pelu ododo, lai si eri jije alagabagebe. Eyi a maa waye nipa fifi idi mule ninu Kristi, ati pe ki ise pe ki a maa lo si eto ijo nikan. O nilo ifaraji fun adura, sise ayewo Iwe Mimo, nini ibasepo pelu Kristi ati awon eniyan Olorun, pelu igbe aye mimo. Ko si ohun ti o le je otito ayafi ninu, ati pelu Kristi. Aisododo wopo ninu aye wa yii tori pe pupo ninu wa ni a ko tii fi Kristi si aaye ti o to si I, ati pelu eto idajo wa, koda ninu ijo Olorun.
*AWON KOKO ADURA:*
1. Oluwa o, je ki Emi Re kun okan mi ki O si gba mi kuro ninu oniruuru ero ibi ati asan.
2..Emi Kristi, mu mi dagba soke, ki n le wa ni ifaraji si ohun ti o to, ti o ye ti o si je ti Olorun.
3.Oluwa o, gba awujo wa kuro ninu aiwa-bi-Olorun, aisododo, etan, ati gbogbo iwa buburu ti a n ri lonii.
*