30/09/2018
SUNDAY 30-09-2018.
MESSAGE BY REV'D M.A. AYANLUDE.
BIBELI KIKA: EFESU 5:21-33
ORI ORO: AWON NKAN SI TUN KU TI A O TI SE
Ni opo igba nigba ti idile ko ba ri bi a se n fe, opo ipa ni ao ti sa, lati mu ki nkan ri bi o se ye, pelu gbogbo igbiyanju wa, nkan ki isaba ri bi a se n fe, eyi mu ki oro ile elomiran su u, debi pe won ti gba kamu, awon miran ti gba ilakoja won gege bi agbelebu, elomi-ran gba pe, awon koni ori idile to dara, eyi mu ki Ijo Olorun kun fun awon okan ti ikoro kun inu okan won, eyi ki ise ife Olorun. Ohun ti o wa ni okan Olorun ni pe ki a je oluranlowo fun ara wa, ti ko ba wa ti ri bee, aje pe; awon nkan si tun ku ti a o ti se. Ibere ni pe, kinni awon ohun naa?
• A O TI GBADURA FUN ENIKEJI WA.
Looto ko si eni ti yoo ni isoro ti ko ni gbadura ki isoro yen le lo. Sugbon otito ti o daju ni pe, a ma so-ro fun wa pupo, lati fi enikeji wa se koko adura wa, awon obinrin tile n se die, sugbon ninu ogorun Okunrin tipa ni ao fi ri marun ti o n gba'we fun Aya tabi enikeji re, awa Yoruba gba wipe, "Ohun to dara n fe adura ki o le ma dara si, eyi ti ko dara naa n fe adura ki o le dara" o dami loju pe adura olododo yo sise agbara.
• A O TI SE IWADI ISORO ENIKEJI WA.
Ti ara eniyan ko ba ya ti won ba gbe lo si ile iwosan, ohun akoko ti o ma wa ye nipe, akose-mose onisegun yo se ayewo lati mo kinni isoro ti o n fa ai-san, opo wa mo pe enikeji wa ko se bi o se ye, sugbon ohun ti ko fi je ko se bi o se ye, a ki i saaba farabale lati mo. Tori naa, ohun miran ti o tun ku ti o ye ki a se ni lati mo kinni isoro enikeji wa.
• A O TI MO ARA WA TO.
N je a le so pe, a mo enikeji wa bi o ti ye, yato si ohun ti a so fun ara wa pe a je, n je a se iwadi iru eni ti eni yen je, n je a mo, n je a je ki o mo wa, awa melo lo ye pe ai-mo enikeji wa le se okunfa ai tesiwaju idile, otito to daju nipe eni ti a o ba mo yo soro lati ba gbe ati lati tesiwaju pelu re.
• A O TI GBA FUN ARA WA.
Otito kan wa, ti o si daju, ko si eni to wa ti ko ni aleebu, Jesu fi idi otito yii mule pe eni rere kan ko si, o si ye ko ye wa pe ki ise gbogbo nkan ni a le fi ogbon wa tunse, awon nkan kan wa ti o ti wo, ti ko si le to mo, tori naa, ohun ti iba dara ni pe, ki a gba ara wa bi a ba ti ri, ki a gba wipe Olorun nikan ni ko ni aleebu; ile kan naa koni a ti jade, tori naa die die ni ao mo jo ara wa.
• A O TI FUN ARA WA NI AKOKO.
Eniyan ti o ti ju odun meedogun lo ki a to dapo, ti a awa fe ki eni yen yipada laarin odun meta, iyen yo soro, agbodo gba wipe, suuru wa yo mu eso to dara wa, nigba ti a ba fi suuru fi ara daa pelu ara wa, ohun ti ko dara yo pada ri bi o se ye ko ri.