29/06/2025
This was a great and powerful ministration ,S COVENANT GLORIOUS ASSEMBLY.
(Agbowa ogijo ogun state)
Ministration to awake the weak soldiers of Christ and to preach the gospel to the people whom they are in bo***ge and to the lost sheep,s
ROMU 8:1 NJẸ ẹbi kò si nisisiyi fun awọn ti o wà ninu Kristi Jesu, awọn ti kò rìn nipa ti ara, bikoṣe nipa ti Ẹmí. There is therefore now no condemnation to them which are in Christ Jesus, who walk not after the flesh, but after the Spirit.
ROMU 8:2 Nitori ofin Ẹmí ìye ninu Kristi Jesu ti sọ mi di omnira lọwọ ofin ẹ̀ṣẹ ati ti ikú. For the law of the Spirit of life in Christ Jesus hath made me free from the law of sin and death.
ROMU 8:3 Nitori ohun ti ofin kò le ṣe, bi o ti jẹ alailera nitori ara, Ọlọrun rán Ọmọ on tikararẹ̀ li aworan ara ẹ̀ṣẹ, ati bi ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ, o si da ẹ̀ṣẹ lẹbi ninu ara: For what the law could not do, in that it was weak through the flesh, God sending his own Son in the likeness of sinful flesh, and for sin, condemned sin in the flesh:
ROMU 8:4 Ki a le mu ododo ofin ṣẹ ninu awa, ti kò rin nipa ti ara, bikoṣe nipa ti Ẹmí. That the righteousness of the law might be fulfilled in us, who walk not after the flesh, but after the Spirit.
ROMU 8:5 Nitori awọn ti o wà nipa ti ara, nwọn a mã ro ohun ti ara; ṣugbọn awọn ti o wà nipa ti Ẹmí, nwọn a mã ro ohun ti Ẹmí. For they that are after the flesh do mind the things of the flesh; but they that are after the Spirit the things of the Spirit.
ROMU 8:6 Nitori ero ti ara ikú ni; ṣugbọn ero ti Ẹmí ni iye ati alafia: For to be carnally minded is death; but to be spiritually minded is life and peace.
ROMU 8:7 Nitori ero ti ara ọtá ni si Ọlọrun: nitori ki itẹriba fun ofin Ọlọrun, on kò tilẹ le ṣe e. Because the carnal mind is enmity against God: for it is not subject to the law of God, neither indeed can be.
ROMU 8:8 Bẹ̃li awọn ti o wà ninu ti ara, kò le wù Ọlọrun. So then they that are in the flesh cannot please God.
ROMU 8:9 Ṣugbọn ẹnyin kò si ninu ti ara, bikoṣe ninu ti Ẹmí, biobaṣepe Ẹmí Ọlọrun ngbe inu nyin. Ṣugbọn bi ẹnikẹni kò ba ni Ẹmí Kristi, on kò si ninu ẹni tirẹ̀. But ye are not in the flesh, but in the Spirit, if so be that the Spirit of God dwell in you. Now if any man have not the Spirit of Christ, he is none of his.
ROMU 8:10 Bi Kristi ba si wà ninu nyin, ara jẹ okú nitori ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn ẹmí jẹ iyè nitori ododo. And if Christ be in you, the body is dead because of sin; but the Spirit is life because of righteousness.
ROMU 8:11 Ṣugbọn bi Ẹmí ẹniti o jí Jesu dide kuro ninu okú ba ngbe inu nyin, ẹniti o ji Kristi Jesu dide kuro ninu okú yio fi Ẹmí rẹ̀ ti ngbe inu nyin, sọ ara kikú nyin di ãye pẹlu. But if the Spirit of him that raised up Jesus from the dead dwell in you, he that raised up Christ from the dead shall also quicken your mortal bodies by his Spirit that dwelleth in you.
ROMU 8:12 Njẹ nitorina, ara, ajigbèsè li awa, ki iṣe ara li a jẹ ni gbese, ti a o fi mã wà nipa ti ara. Therefore, brethren, we are debtors, not to the flesh, to live after the flesh.
ROMU 8:13 Nitori bi ẹnyin ba wà ni ti ara, ẹnyin ó kú: ṣugbọn nipa Ẹmí bi ẹnyin ba npa iṣẹ́ ti ara run, ẹnyin ó yè. For if ye live after the flesh, ye shall die: but if ye through the Spirit do mortify the deeds of the body, ye shall live.
ROMU 8:14 Nitori iye awọn ti a nṣe amọ̀na fun lati ọdọ Ẹmí Ọlọrun wá, awọn ni iṣe ọmọ Ọlọrun. For as many as are led by the Spirit of God, they are the sons of God.
ROMU 8:15 Nitori ẹnyin kò tun gbà ẹmí ẹrú lati mã bẹ̀ru mọ́: ṣugbọn ẹnyin ti gbà ẹmí isọdọmọ, nipa eyi ti awa fi nke pé, Abba, Baba. For ye have not received the spirit of bo***ge again to fear; but ye have received the Spirit of adoption, whereby we cry, Abba, Father.
ROMU 8:16 Ẹmí tikararẹ̀ li o mba ẹmí wa jẹrí pe, ọmọ Ọlọrun li awa iṣe: The Spirit itself beareth witness with our spirit, that we are the children of God:
ROMU 8:17 Bi awa ba si jẹ ọmọ, njẹ ajogun li awa, ajogun Ọlọrun, ati ajumọ-jogun pẹlu Kristi; biobaṣepe awa bá a jìya, ki a si le ṣe wa logo pẹlu rẹ̀. And if children, then heirs; heirs of God, and joint-heirs with Christ; if so be that we suffer with him, that we may be also glorified together.
ROMU 8:18 Nitori mo ṣíro rẹ̀ pe, ìya igba isisiyi kò yẹ lati fi ṣe akawe ogo ti a o fihàn ninu wa. For I reckon that the sufferings of this present time are not worthy to be compared with the glory which shall be revealed in us.
ROMU 8:19 Nitori ifojusọ́na ti ẹda nduro dè ifihàn awọn ọmọ Ọlọrun. For the earnest expectation of the creature waiteth for the manifestation of the sons of God.
ROMU 8:20 Nitori a tẹri ẹda ba fun asan, ki iṣe ifẹ rẹ̀, ṣugbọn nitori ẹniti o tẹ ori rẹ̀ ba, ni ireti, For the creature was made subject to vanity, not willingly, but by reason of him who hath subjected the same in hope,
ROMU 8:21 Nitori a ó sọ ẹda tikalarẹ di omnira kuro ninu ẹrú idibajẹ, si omnira ogo awọn ọmọ Ọlọrun. Because the creature itself also shall be delivered from the bo***ge of corruption into the glorious liberty of the children of God.
ROMU 8:22 Nitori awa mọ̀ pe gbogbo ẹda li o jumọ nkerora ti o si nrọbi pọ̀ t**i di isisiyi. For we know that the whole creation groaneth and travaileth in pain together until now.
ROMU 8:23 Kì si iṣe awọn nikan, ṣugbọn awa tikarawa pẹlu, ti o ni akọ́so Ẹmí, ani awa tikarawa nkerora ninu ara wa, awa nduro dè isọdọmọ, ani idande ara wa. And not only they, but ourselves also, which have the firstfruits of the Spirit, even we ourselves groan within ourselves, waiting for the adoption, to wit, the redemption of our body.
ROMU 8:24 Nitori ireti li a fi gbà wa là: ṣugbọn ireti ti a bá ri kì iṣe ireti: nitori tani nreti ohun ti o bá ri? For we are saved by hope: but hope that is seen is not hope: for what a man seeth, why doth he yet hope for?
ROMU 8:25 Ṣugbọn bi awa ba nreti eyi ti awa kò ri, njẹ awa nfi sũru duro dè e. But if we hope for that we see not, then do we with patience wait for it.
ROMU 8:26 Bẹ̃ gẹgẹ li Ẹmí pẹlu si nràn ailera wa lọwọ: nitori a kò mọ̀ bi ã ti igbadura gẹgẹ bi o ti yẹ: ṣugbọn Ẹmí tikararẹ̀ nfi irora ti a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ fun wa. Likewise the Spirit also helpeth our infirmities: for we know not what we should pray for as we ought: but the Spirit itself maketh intercession for us with groanings which cannot be uttered.
ROMU 8:27 Ẹniti o si nwá inu ọkàn wo, o mọ̀ ohun ti inu Ẹmí, nitoriti o mbẹbẹ fun awọn enia mimọ́ gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun. And he that searcheth the hearts knoweth what is the mind of the Spirit, because he maketh intercession for the saints according to the will of God.
ROMU 8:28 Awa si mọ̀ pe ohun gbogbo li o nṣiṣẹ pọ̀ si rere fun awọn ti o fẹ Ọlọrun, ani fun awọn ẹniti a pè gẹgẹ bi ipinnu rẹ̀. And we know that all things work together for good to them that love God, to them who are the called according to his purpose.
ROMU 8:29 Nitori awọn ẹniti o ti mọ̀ tẹlẹ, li o si ti yàn tẹlẹ lati ri bi aworan Ọmọ rẹ̀, ki on le jẹ akọbi larin awọn arakunrin pupọ. For whom he did foreknow, he also did predestinate to be conformed to the image of his Son, that he might be the firstborn among many brethren.
ROMU 8:30 Awọn ti o si ti yàn tẹlẹ, awọn li o si ti pè: awọn ẹniti o si ti pè, awọn li o si ti dalare: awọn ẹniti o si ti dalare, awọn li o si ti ṣe logo. Moreover whom he did predestinate, them he also called: and whom he called, them he also justified: and whom he justified, them he also glorified.
ROMU 8:31 Njẹ kili awa o ha wi si nkan wọnyi? Bi Ọlọrun bá wà fun wa, tani yio kọ oju ija si wa? What shall we then say to these things? If God be for us, who can be against us?
ROMU 8:32 Ẹniti kò da Ọmọ on tikararẹ̀ si, ṣugbọn ti o jọwọ rẹ̀ lọwọ fun gbogbo wa, yio ha ti ṣe ti kì yio fun wa li ohun gbogbo pẹlu rẹ̀ lọfẹ? He that spared not his own Son, but delivered him up for us all, how shall he not with him also freely give us all things?
ROMU 8:33 Tani yio ha kà ohunkohun si ọrùn awọn ayanfẹ Ọlọrun? Ihaṣe Ọlọrun ti ndare? Who shall lay any thing to the charge of God's elect? It is God that justifieth.
ROMU 8:34 Tali ẹniti ndẹbi? Ihaṣe Kristi Jesu ti o kú, ki a sa kuku wipe ti a ti ji dide kuro ninu okú, ẹniti o si wà li ọwọ́ ọtun Ọlọrun, ti o si mbẹ̀bẹ fun wa? Who is he that condemneth? It is Christ that died, yea rather, that is risen again, who is even at the right hand of God, who also maketh intercession for us.
ROMU 8:35 Tani yio ha yà wa kuro ninu ifẹ Kristi? ipọnju ni, tabi wahalà, tabi inunibini, tabi ìyan, tabi ìhoho, tabi ewu, tabi idà? Who shall separate us from the love of Christ? shall tribulation, or distress, or persecution, or famine, or nakedness, or peril, or sword?
ROMU 8:36 Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Nitori rẹ li a ṣe npa wa kú li gbogbo ọjọ; a nkà wa si bi agutan fun p**a. As it is written, For thy sake we are killed all the day long; we are accounted as sheep for the slaughter.
ROMU 8:37 Ṣugbọn ninu gbogbo nkan wọnyi awa jù ẹniti o ṣẹgun lọ nipa ẹniti o fẹ wa. Nay, in all these things we are more than conquerors through him that loved us.
ROMU 8:38 Nitori o da mi loju pe, kì iṣe ikú, tabi ìye, tabi awọn angẹli, tabi awọn ijoye, tabi awọn alagbara, tabi ohun ìgba isisiyi, tabi ohun ìgba ti mbọ̀, For I am persuaded, that neither death, nor life, nor angels, nor principalities, nor powers, nor things present, nor things to come,
ROMU 8:39 Tabi òke, tabi ọgbun, tabi ẹda miran kan ni yio le yà wa kuro ninu ifẹ Ọlọrun, ti o wà ninu Kristi Jesu Oluwa wa. Nor height, nor depth, nor any other creature, shall be able to separate us from the love of God, which is in Christ Jesus our Lord.