Ori-Oke Majemu Emi-Oluwa Ministries

Ori-Oke Majemu Emi-Oluwa Ministries ORUKỌ JESU ORUKỌ TO LAGBARA NI

22/02/2026
22/02/2026

Ìjọ Aposteli Kristi
Nàìjíríà Àti Òkè Òkun

ILÉ Ẹ̀KỌ́ ỌJỌ́ ÌSINMI

Akori Gbooro:
BÍBÉLÌ NÁÀ: ỌRỌ/ÌṢẸ ỌLỌ́RUN SI ÈNÌYÀN

Oṣù Kínní si oṣù Kejila 2026

Isọri I:
Ìṣẹda Ọ̀rọ̀/Ìṣẹ́ náà àti Imisi Bíbélì

February 22, 2026

Ẹ̀KỌ́ 6

Akori:
Ofin Ọlọ́run: Majẹmu Àwọn Ènìyàn Rẹ.

AKỌSÓRÍ:
Ǹjẹ́ nisinsin yii, bi ẹyin ba fẹ gbà ohun Mi gbọ nitootọ, tiẹ o si pa Majẹmu Mi mọ, nigba naa ni ẹyin yoo jẹ ìṣúra fun Mi ju gbogbo eniyan lọ: nitori gbogbo aye ni ti Emi. Ẹyin o si ma a jẹ ìjọba àlùfáà fun mi, ati orílẹ̀ ede mimọ. Wọnyii ni ọrọ ti iwọ yoo sọ fun awọn ọmọ Ísírẹ́lì (Eksodu 19:5-6).

Ofin Olorun jẹ Majẹmu Mimọ, ti on tọ awọn eniyan Rẹ ninu ifẹ, idajọ ati ododo, ti o n mu ìgbàgbọ́, ìṣọkan ati ìjọsìn gbilẹ sii.

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ

AKỌSÓRÍ wa lati inu Ẹ́kísódù 19:5-6 sọrọ nipa Ibaṣepọ ìjìnlẹ̀ pẹlu awọn ènìyàn Rẹ. O ṣe atẹnumọ pe Majẹmu yii wá pẹlu ileri Lati pẹlu titori/ìdí-ìgbọràn. Ere fun ìgbọràn ko ni afiwe -pe a yan ènìyàn bi "ìṣúra iyebiye" Ọlọ́run, ara "ìjọba alufaa", ati "orílẹ̀ ede mimọ". Eyin sọrọ nipa ọkan Bibeli, eyi ti o jẹ ọna ti Ọlọrun n gba ba eniyan sọ̀rọ̀ ti On fun wa ni àwọn ofin, àṣẹ ati ìlérí Rẹ fun awọn ti wọn n fẹ lati maa tọ Ọ lẹyin. Ki ìṣe awọn ofin lásán ṣùgbọ́n ìṣẹ́ fun ibaṣepọ ti o ni ifaraji nínú pẹlu Ọlọ́run. Iwe Mimọ yii ran wa leti pe ofin Ọlọ́run ko wa lati jẹ ajaga; o jẹ majẹmu ti o sọ bi O ṣe n ni ibaṣepọ pẹlu wa-Awọn eniyan Rẹ-ti o si pe wa sínú isopọ ti o jinleẹ ti o si ni itumo pẹlu Rẹ. A gbàdúrà ki a ri oore ọfẹ lati kun oju oṣùwọn ireti àtọ̀runwá yii gba.

ÀṢÀRÒ LATI INU BÍBÉLÌ

Mon. 16: Bi Ìwọ Ba N Fẹ, Ti O si gbọran... (Isa. 1:19)

Tue. 17: Bi Ìwọ Ba farabalẹ̀ lati Gbọ (Deut. 28:1-20)

Wed. 18: Ti lwọ ba Si Fetisi... (Eks. 15:26)

Thur. 19: Bi Ìwọ Ko Ba Fetisi... (Deut. 28:15)

Fri. 20: Ti Awọn Eniyan Mi... (2 Kro. 7:14)

Sat. 21: Emi Yoo Si Jẹ Ọlọ́run Yin (Eks. 6:7, 19:5-6)

ÀṢÀRÒ FUN ÌFỌKÀNSÌN

1. Gbigbọran si ohùn Ọlọ́run maa n mu ìbùkún wa gẹgẹ bi ofin Rẹ ti ję itoni ti o n funni ni iye fun ire aye wa.

2. Ti a ba gbọ́ràn si ofin Ọlọ́run, a o ya wa sọtọ, a o si bukun wa. Majẹmu ayérayé Rẹ pe wa lati maa gbe pẹ̀lú ojúṣe, ki ìṣe ireti nikan ni o mu wa.

ẸSẸ BÍBÉLÌ FUN IPILẸ Ẹ̀KỌ́ DEUTERONOMI 5:1-22

ILEPA ATI ÀWỌN ERONGBA

ILEPA: Lati ṣàwárí ìṣẹ̀dá ofin Ọlọ́run gẹgẹ bii Majẹmu, ati Pataki rẹ si awọn eniyan Rẹ.

ÀWỌN ERONGBA: Ni opin ẹko yii, awọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọdọ le:

i. Ṣalaye Ìṣẹda/ẹda májẹmu Ọlọ́run ati ofin ti o fi fun awọn eniyan Rẹ;

ii. Ṣafihan pe ìgbọràn si ofin Ọlọ́run ni isopọ mọ awọn ìbùkún Rẹ ati awọn ileri Májẹmu.

iii. Ṣafihan awọn ami ṣíṣamulo awọn ilana majẹmu naa bi igbe aye ojoojumọ wọn lati maa gbe gẹgẹ bi eniyan mimọ ati orílẹ̀ ede ti a yan.

IFAARA

ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: EKSODU 19:5; LEFTTIKU 11:44; DEUTERONOMI 28:1-2, 15; JEREMIAH 31:33-34.
Ninu ẹkọ wa ti o kọja, ERONGBA BIBELI: ETO ỌLỌ́RUN FUN IRAN ENIYAN, a wo bi Bíbélì ṣe ṣafihan eto Ọlọ́run ti ko ni afiwe ti o ni fun wa. Ni ọsẹ yii, a o wo Ofin Ọlọ́run: Majẹmu pẹlu Awọn Eniyan Rẹ.

Nini oye pe ofin Ọlọ́run jẹ Majẹmu ṣe pataki pupọ si ìgbàgbọ́ Kristieni wa. Ofin Rẹ fi ẹda Rẹ han wa, ohun ti o n reti lati ọdọ awọn eniyan Rẹ ati ọna lati ni iriri àwọn ibukun Rẹ. Ṣugbọn ofin yii ki ìṣe awọn ilana kan sa; o jẹ àdéhùn nífẹ̀ẹ́ ti on pe fun ìgbọran.

Ninu Majẹmu Laelae, àwọn ọmọ Isireli ni a yan lati jẹ awọn ènìyàn ọ̀tọ̀ Ọlọ́run, ti a ya-sọtọ lati ara araye ti o ku nípasẹ̀ ifaraji wọn fun ofin Rẹ. Ofin yii ko kan wa fun wọn lasan - o wa lati fi han fun araye Ẹniti Ọlọrun ìṣe. Ilana yii tiba wa mu lonii, bii ọrọ Ọlọ́run yoo ti maa tọ wa lábẹ́ Majẹmu Tuntun nípasẹ̀ Jésù Kristi.

KOKO Ẹ̀KỌ́

I. Ẹ̀DÁ/IRI MAJẸMU OFIN ỌLỌ́RUN

II. ÀWỌN IBUKUN ATI OJÚṢE OFIN NAA

ITUPALẸ Ẹ ẸKỌ

I. Ẹ̀DÁ/IRI MÁJẸ̀MÚ OFIN ỌLỌ́RUN (Eks. 19:5; Lef. 11:44)

Ǹjẹ́ nisinsin yii, bi ẹyin ba fẹ gba ohùn Mi gbọ nitootọ, ti ẹ o si pa majẹmu Mi mọ... (Eks. 19:5).

a. Eks. 19:5: ofin Ọlọ́run ki ìṣe àkójọpọ ilana; o jẹ ìtọ́ni àtọ̀runwá ti o n sọ ifẹ Ọlọ́run fun awọn ènìyàn Rẹ, ti o n pe wọn lati tẹtisi ohun Rẹ ki wọn si pa majẹmu Rẹ mọ.

b. Ofin naa jẹ ẹbun, ti o n fi bi àwọn eniyan Ọlọ́run yóò ṣe maa huwa ni ọna ti yóò maa fi ọwọ fun Un. Ki ìṣe ofin nipa ati moribọ ṣùgbọ́n lati ni oye ati lati tẹle ìfẹ́ Ọlọ́run (wo Mat. 5:17).

d. Ẹsẹ 6: Ọlọ́run pe awọn eniyan Rẹ lati jẹ ara "ijọba alufaa" ati "orílẹ̀ ede mimọ", ti wọn ba gbọran si I lẹnu. Ofin jẹ ibaṣepọ. Ki ìṣe nipa ilana, ṣugbọn nini ibaṣepọ ti o jinlẹ pẹlu Ọlọ́run.

e. Ofin Ọlọ́run jẹ ipe lati maa gbe ni sisunmọ Ọ, ki a maa ṣafihan iwa mimọ ati erongba Rẹ. Bakan naa ni a pe wa lati jẹ eniyan mimọ ti a yan. (I pet. 2:9). Ǹjẹ́ eyi juwe rẹ bi?

ẹ. Lef. 11:44: Ofin Ọlọ́run ṣafihan iwa mimọ Rẹ bẹẹni o si pe wa ki a gbe igbe aye mimọ/funfun (wo I Pet. 1:15,16). O jẹ nipa iyipada inu, ki ìṣe ofin ṣa ati nipasẹ Jésù nikan, ni a fi le kun oju òṣùwọ̀n Rẹ.

f. Ofin Ọlọ́run ju ilana lasan lọ; o jẹ majẹmu ti o n ṣàtúnṣe ibaṣepọ wa pẹlu Rẹ, bẹẹni o sin pe wa lati gbe igbe aye iwa mimọ. Ki ìṣe fun awọn ọmọ Isireli nikan ṣugbọn fun gbogbo onigbagbọ lonii.

II. ÀWỌN IBUKUN ATI OJÚṢE OFIN NAA (Deut. 28:2, 15; Jer. 31:33-34)
Yoo si ṣe, bi ìwọ ba farabalẹ̀ gbọ ohun OLUWA Ọlọ́run rẹ... gbogbo ìbùkún wọnyii yóò si ṣẹ sori rẹ (Deut.28:1-2).

a. Deut. 28:1-2: Ọlọ́run ṣèlérí àwọn ìbùkún alaafia, ìṣe rere ati Ìgbọràn maa n mu aabo - fun awọn ti wọn ba gbọran si I lẹnu. ojurere Rẹ wa. Tètè kọ wa ijọba Ọlọ́run naa, a o si fi eyi ti o ku kun un (Mat. 6:33).

b. Ẹsẹ 15: Ìgbọràn maa n wa pẹlu ojúṣe lati maa gbe igbe aye nipa òfin Ọlọ́run. Àìgbọràn maa n mu ijiya wá pẹlu iyapa kúrò ninu awọn ibukun Rẹ. Iyan wa ṣe Pataki (wo Gal. 6:7).

d. Jer. 31:33: Ọlọ́run jẹ olootọ si awọn ènìyàn Rẹ nigba gbogbo. Majẹmu Rẹ ni o gbe ka ori òtítọ́ Rẹ, ki ìṣe pipe wa (2 Tim. 2:13). Ani nigba ti a ba kuna, Oun faraji síbẹ̀ fun wa. Majẹmu Tuntun nínú Jésù fun wa ni imubọsipọ ati ìrètí fun ilaja.

e. ẹsẹ 33,34: Ìlérí Ọlọ́run lati jẹ Ọlọ́run wa ni o wa ninu òtítọ́ Rẹ ti ki yipada. Nigba ti ohunkóhun ko ba ya wa kuro ninu ìfẹ́ Rẹ̀ (Rom. 8:38-39). Ibaṣepọ wa pẹlu Rẹ gba igbagbọ ati ìgbọràn ti o n tẹsiwaju. Isòtítọ́ Rẹ ki ìṣe awawi fun àṣìṣe àìgbọràn.

ẹ. Nipa gbigbọran si ofin Ọlọ́run, a o ni iriri ibukun ati ojúṣe. Ani bi a ba tilẹ kuna, isotitọ Ọlọ́run ti kii yẹ yoo fun wa ni anfaani lati pada ki a si mu wa bọ sipo.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TI A RI KỌ
1. Ìgbọràn a maa ṣi awọn ibukun Ọlọ́run. Titẹle àṣẹ Rẹ maa n pe ojurere Rẹ ati ere wa.

2. Majẹmu Ọlọ́run jẹ ibaṣepọ, ki ìṣe Ìṣẹ́ àgbaṣe . O jẹ ipe lati gbẹkẹle E, gbọ́ràn ki a si faraji fun ìfẹ́ Rẹ.

ÀWỌN IBEERE
1. Kin ni o tumọsi lati jẹ ara "Ìjọba alufaa" ati "orilẹ ede mimọ" (Eks. 19:6) ati pe báwo ni eyi ṣe wa ni ibamu pẹlu ẹdá ofin Ọlọ́run ati majẹmu?

2. Bawo ni a ṣe le ṣamulo ilana ìgbọràn ati ibukun ninu igbe aye wa ojoojumọ, paapaa julọ ninu ibaṣepọ wa pẹlu Ọlọ́run?

ÀWỌN ÌDÁHÙN TI A DABAA FUN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ 1
* Jíjẹ "alufaa ijọba" tumọsi pe a ya awọn ènìyàn Ọlọ́run sọtọ lati sin In, ki o si sọ ọrọ Rẹ fun àwọn ẹlòmíràn.

* Orilẹ ede mimọ " tumọsi pe awọn ènìyàn Ọlọ́run yẹ ki wọn maa gbe ni ọna ti yoo maa fi mimọ, ati ododo Rẹ han lọna ti o yatọ si ti aye.

* Eyi ni iṣe pẹlu ofin ati majẹmu Ọlọ́run nitori pe ofin ni o pèsè ìtọ́ni fun bi o ṣe yẹ ki awọn eniyan Rẹ o maa gbe igbe aye wọn gẹgẹ bi aṣojú Rẹ ti on ṣafihan iwa mimọ ati erongba Rẹ.

* Majẹmu Ọlọ́run pẹlu Isireli pé wọn si ìgbọràn, pẹlu ileri pe wọn yoo jẹ imọlẹ si awọn orilẹ ede, ki wọn o maa fi iwa Ọlọrun han nipa Ìṣe wọn.

ÌDÁHÙN SI ÌBÉÈRÈ 2
* A le gbọran si Ọlọ́run lẹnu nipa gbígbé igbe aye wa ni ibamu pẹlu ọrọ Rẹ ki a si maa yan iyan ti yoo maa mu ọwọ̀ ba A ni igbe aye wa ojoojumọ (O.D. 119:105).

* Gbigbọran si Ọlọrun maa n yọrisi awọn ibukun bii alaafia, ayọ ati isopọ ti o jinlẹ pẹlu Rẹ. O jẹ nini ibaṣepọ ìgbẹ́kẹ̀lé ati ifẹ, ki ìṣe ki o kan maa tẹle ofin sa (Jhn. 14:15).

* Ìgbọràn le nira, a maa mu wa sunmọ Ọlọ́run, a sọ aye wa pọ mọ erongba Rẹ bẹẹni a si maa pe aabo ati ìpèsè Rẹ fun wa (Deut. 28:1-2).

ÀMÚLÒ FUN ÌGBÉ AYE ẸNI
Finuro idile ti o pinnu lati tọ ọmọ ní bi ọrọ Ọlọrun ti sọ/wi pẹlu wahala ati awọn idiwọ inu aye lonii. Awọn obi si yan lati tẹle ìtọ́ni Ọlọ́run, ti wọn si n kọ awọn ọmọ wọn ni ofin Rẹ, ti wọn si fi ọjọ ọla wọn le E lọwọ. Bi wọn ba ti n ṣe eyi, wọn yóò bẹrẹ si ri awọn ìbùkún ti yoo maa yọjú àlàáfíà ninu ile wọn, ìṣọ̀kan ninu ibaṣepọ wọn ati ìdàgbàsókè ti ẹmi ninu awọn ọmọ wọn. Eyi ṣafihan agbára gbigbe ni ibamu pẹlu majẹmu Ọlọ́run. Ti a ba gbọran si I lẹnu, awọn ileri àlàáfíà ati ìbùkún ni yoo wa si ìmúṣẹ lotitọ ninu aye wa.

IGUNLẸ
Ofin Ọlọ́run ki ìṣe akojọpọ awọn ilana; o jẹ majẹmu pẹlu awọn ènìyàn Rẹ, àdéhùn àtọ̀runwá ti o fi gbongbo múlẹ̀ ninu ìfẹ́ ati iwa mimọ Rẹ. Bi a ba ti n gbọ́ràn si ohun Ọlọ́run ti a si n pa ofin Rẹ mọ, a ni anfaani lati gbe bi ẹni iyan Rẹ, ti a bukun fun pẹlu awọn ileri ati iwalaaye Rẹ. Nípasẹ̀ ìgbọràn si ofin Ọlọ́run, a ti mu erongba wa ṣe gẹgẹ bi orílẹ̀ ede mimọ, ti a yasọtọ fun ògo Rẹ. Eyi ni pataki ẹkọ ti a ṣẹ̀ṣẹ̀ pari yii. Maṣe gbagbe!

Àkíyèsí

22/02/2026

CHRIST APOSTOLIC CHURCH
Nigeria & Overseas

SUNDAY SCHOOL LESSON

Theme:
The BIBLE: God's Message to Man

January - December 2026

Unit 1:
The Nature, Message and Inspiration of the Bible

February 22, 2026

Lesson 6

Topic:
God's Law: A Covenant With His People

Memory Scripture:
Now therefore, if you will indeed obey My voice and keep My covenant, then you shall be a special treasure to Me above all people; for all the earth is Mine. And you shall be to Me a kingdom of priests and a holy nation (Exodus 19:5-6).

God's law is a sacred covenant, guiding His people in love, justice, and righteousness, fostering faith, harmony, and devotion.

BRIEF COMMENT
The memory emory scripture from Exodus 19:5-6 captures the essence of God's deep, covenantal ntal relationship with His people. It emphasises that this relationship comes with a promise, but also with a condition-obedience. The reward for obedience is incredible-being chosen as God's "special treasure" part of a "kingdom of priests", and a "holy nation". This speaks directly to the heart of the Bible, which is God's way of reaching out to humanity, giving us His laws, commandments and promises for those willing to follow. It is not just a list of rules but a framework for a committed relationship with God. This scripture reminds us that God's law is not meant to be a burden; it is a covenant that defines how He interacts with us-His people-and calls us into a deeper, more meaningful connection with Him. May we find His grace to meet this divine expectation.

DEVOTIONAL BIBLE READINGS
Mon. 16: If You Are Willing And Obedient... (Isa. 1:19)

Tue. 17: If You Will Hearken... (Deut. 28:1-2)

Wed. 18: If You Will Diligently Hearken... (Exo. 15:26)

Thu. 19: If You Will Not Hearken... (Deut. 28:15)

Fri. 20: If My People... (2 Chro. 7:14)

Sat. 21: I Will Be Your God (Exo. 6:7; 19:5-6).

DEVOTIONAL THOUGHTS
1. Obeying God's voice brings blessings as His law is a life-giving guide for our well-being.

2. When we obey God's law, we are set apart and blessed. His timeless covenant does not only bring us hope but also calls us to live with responsibility.

BACKGROUND SCRIPTURE: Deuteronomy 5:1-22

AIM AND OBJECTIVES

AIM: To explore the nature of God's law as a covenant, and its significance for His people.

OBJECTIVES: By the end of this lesson, learners should be:
i. able to explain the nature of God's covenant and the law He gives to His people;

ii. able to show that obedience to God's law is tied to His blessings and covenant promises; and

iii. showing signs of applying the principles of the covenant in their daily lives to live as a holy and chosen people.

INTRODUCTION
TEXTUAL SOURCES: EXODUS 19:5; LEVITICUS 11:44; DEUTERONOMY 28:1-2, 15; JEREMIAH 31:33-34
In our last lesson, The Bible's Purpose: God's Plan for Humanity, we looked at how the Bible reveals God's incredible plan for us. This week, we are going to explore God's Law: A Covenant With His People.

Understanding God's law as a covenant is really important to our Christian faith. His Law shows us His nature, what He expects from His people and the way to experience His blessings. But this covenant isn't just a set of rules; it is a loving agreement that calls for obedience.

In the Old Testament, the Israelites were chosen to be God's special people, set apart from the rest of the world through their commitment to His Law. This relationship wasn't just for them-it was meant to show the world who God is. The same principles still apply to us today, as God's Word continues to guide us under the New Covenant through Jesus Christ.

LESSON OUTLINE
I. THE COVENANT NATURE OF GOD'S LAW

II. THE BLESSINGS AND RESPONSIBILITIES OF THE LAW

LESSON EXPOSITION

I. THE COVENANT NATURE OF GOD'S LAW (Exo. 19:5; Lev. 11:44)
Now therefore, if you will indeed obey My voice and keep My covenant... (Exo. 19:5).

a) Exo. 19:5: God's Law isn't just a set of rules; it is a divine guide reflecting God's will for His people, calling them to listen to His voice and keep His covenant.

b) The Law is a gift, showing God's people how to live in a way that honours Him. It isn't just rules about survival but understanding and following God's desires (cf. Matt. 5:17).

c) v. 6: God calls His people to be a "kingdom of priests" and a "holy nation", if they obey Him. The Law is a relationship. It isn't just about rules, but about building a deeper relationship with God.

d) God's Law is an invitation to live closely with Him, reflecting His holiness and purpose. We are also called to be a holy, chosen people (1 Pet. 2:9). Does that describe you?

e) Lev. 11:44: God's Law reflects His holiness and calls us to live pure lives (cf. 1 Pet. 1:15,16). It is about inner change, not just rules, and through Jesus alone, we can live by His standards.

f God's Law is more than rules; it is a covenant that shapes our relationship with Him and calls us to live in His holiness. It is not just for the Israelites, but for all believers today.

II. THE BLESSINGS AND RESPONSIBILITIES OF THE LAW (Deut. 28:1-2,15; Jer. 31:33-34)
If you will diligently obey the voice of the LORD your God... all these blessings shall come upon you (Deut. 28:1-2).

a) Deut. 28:1-2: God promises blessings-peace, prosperity and protection-to those who obey Him. Obedience brings His favour. Seek God's kingdom first and everything else follows (Matt. 6:33).

b) v. 15: Obedience comes with the responsibility to live by God's commands. Disobedience brings penalties, including separation from His blessings. Our choices matter (cf. Gal. 6:7).

c) Jer. 31:33: God is always faithful to His people. His covenant is built on His faithfulness, not our perfection (2 Tim. 2:13). Even when we fall short, He remains committed to us. The New Covenant in Jesus offers restoration and hope for reconciliation.

d) vv. 33,34: God's promise to be our God is rooted in His unchanging faithfulness. While nothing separates us from His love (Rom. 8:38-39), our relationship with Him requires continued faith and obedience. His faithfulness is not an excuse for disobedience.

e) By obeying God's Law, we experience both blessings and responsibility. And even when we fall short, God's unwavering faithfulness offers us the chance to return and be restored.

LESSONS DERIVED
1. Obedience unlocks God's blessings. Following His commands invites His favour and rewards.

2. God's covenant is a relationship, not a contract. It is a call to trust, obey and commit to His love.

QUESTIONS
1. What does it mean to be a "kingdom of priests" and "a holy nation" (Exodus 19:6) and how does this relate to the nature of God's Law and covenant?

2. How can we apply the principles of obedience and blessing in our daily lives, especially in our relationship with God?

SUGGESTED ANSWERS TO QUESTIONS

ANSWERS TO QUESTION 1
* Being a "kingdom of priests" means that God's people are set apart to serve Him and represent Him to others.

* A "holy nation" means that God's people are to live in a way that reflects His purity and righteousness, distinct from the world.

* This relates to God's Law and covenant because the Law provides the guidelines for how His people are to live as His representatives, reflecting His holiness and purpose.

* God's covenant with Israel called them to obedience, with the promise that they would be a light to the nations, showing God's t 's character through their actions.

ANSWER TO QUESTION 2
* We can obey God by living according to His Word and making choices that honour Him in our everyday lives (Ps. 119:105).

* Obeying God leads to blessings like peace, joy and a deeper connection with Him. It is about building a relationship of trust and love, not just following rules (Jn. 14:15).

* While obedience can be tough, it brings us closer to God, aligning our lives with His purpose and inviting His protection and provision (Deut. 28:1-2).

LIFE APPLICATION
Consider a family that decides to raise their children according to God's Word, despite the pressures and distractions of today's world. The parents choose to follow God's guidance, teaching their children His commandments and trusting Him with their future. As they live out this commitment, they begin to see blessings unfold-peace in their home, harmony in their relationships and spiritual growth in their children. This shows the power of living in line with God's covenant. When we obey Him, His promises of peace and blessings are faithfully fulfilled in our lives.

CONCLUSION
God's Law is not only a set of instructions; it is a covenant with His people, a divine agreement rooted in His love and holiness. As we obey God's voice and keep His commandments, we are privileged to live as His chosen people, blessed with His promises and presence. Through obedience to God's law, we fulfil our purpose as a holy nation, set apart for His glory. This is the import of the lesson we just concluded. Don't forget!

NOTE

Happy New Month
02/02/2026

Happy New Month

02/02/2026

CHRIST APOSTOLIC CHURCH
[Nigeria and Overseas]

THE LIVING WATER (January-December, 2026)

DAILY DEVOTIONAL GUIDE

DATE:
Monday, 2nd February, 2026

TOPIC:
TRUSTING GOD'S PROVISION

MEMORISE

And my God shall supply all your need according to His riches in glory by Christ Jesus (Philippians 4:19).

READ:
Philippians 4:14-20

[1]. Nevertheless you have done well that you shared in my distress.

[15]. Now you Philippians know also that in the beginning of the gospel, when I departed from Macedonia, no church shared with me concerning giving and receiving but you only.

[16]. For even in Thessalonica you sent aid once and again for my necessities.

[17]. Not that I seek the gift, but I seek the fruit that abounds to your account.

[18]. Indeed I have all and abound. I am full, having received from Epaphroditus the things sent from you, a sweet-smelling aroma, an acceptable sacrifice, well pleasing to God.

[19]. And my God shall supply all your need according to His riches in glory by Christ Jesus.

[20]. Now to our God and Father be glory forever and ever. Amen.

EXPOSITION

God's provision is always tied to His purpose. When He calls us to a specific assignment, He provides all that we need to accomplish it (Php. 4:19). But it is important to remember that His provision is for what He has ordained, not what we have started on our own (Isa. 55:10-11).

When we operate within the framework of God's will, we can trust that He will supply all our needs (2 Cor. 9:8). This doesn't mean there won't be challenges, or times of stretching, but it means we can have confidence that God's resources are sufficient (Eph. 3:20). His provision may come in unexpected ways, but it always comes at the right time (Eccl. 3:1,11).

If we ever feel any lack, it is a good time to step back and assess whether we are operating in alignment with God's plan (Pro. 3:5-6). Are we pursuing His direction, or have we drifted into something of our own making? When we are in God's will, we can rest assured that He will meet every need (Matt. 6:33).

PRAYER POINTS

1. Lord, help me to always patiently wait for Your provision until it comes.

2. Lord, help me to align all areas of my life with your purpose.

3. Lord, I trust You to meet every need as I walk in Your plan.

SUGGESTED HYMN FOR TODAY:
CACGHB: 71

7 7 7 7

1. Let us with a gladsome mind
Praise the Lord, for He is kind;
For His mercies still endure,
Ever faithful, ever sure

2. He, with all-commanding might,
Filled the new-made world with light;
For His mercies still endure,
Ever faithful, ever sure

3. All things living he doth feed,
His full hand supplies their need:
For His mercies still endure,
Ever faithful, ever sure

4. He His chosen race did bless
In the wasteful wilderness:
For His mercies still endure,
Ever faithful, ever sure

5. Let us then with gladsome mind
Praise the Lord, for He is kind:
For His mercies still endure,
Ever faithful, ever sure.

Amen.

EXTRA READING FOR TODAY:
Leviticus 4, 5, 6

Cordially invite you to our Weekly powerful Revival
02/02/2026

Cordially invite you to our Weekly powerful Revival

02/02/2026

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Naijiria àti Oke Okun

OMI IYE NAA, (January- December, 2026)

Ọjọ
AJE (Monday) FEBRUARY 2, 2026.

ÀKÒRÍ:
GBIGBAGBỌ NINU IPESE ỌLỌRUN

AKỌSORI:

Ṣugbọn Ọlọrun mi yio pèse ni kikún fun gbogbo aini nyin, gẹgẹ bi ọrọ̀ rẹ̀ ninu ogo ninu Kristi Jesu (Filipi 4:19).

KA:
Filipi 4:14-20

[14]. Ṣugbọn ẹnyin ṣeun gidigidi niti pe ẹnyin ṣe alabapin ninu ipọnju mi.

[15]. Ẹnyin papa si mọ̀ pẹlu, ẹnyin ara Filippi, pe li ibẹrẹ ihinrere, nigbati mo kuro ni Makedonia, kò si ijọ kan ti o ba mi ṣe alabapin niti gbigbà ati fifunni, bikoṣe ẹnyin nikanṣoṣo.

[16]. Nitori ni Tessalonika gidi, ẹnyin ranṣẹ, ẹ si tun ranṣẹ fun aini mi.

[17]. Kì iṣe nitoriti emi nfẹ ẹ̀bun na: ṣugbọn emi nfẹ eso ti yio mã di pupọ nitori nyin.

[18]. Ṣugbọn mo ni ohun gbogbo, mo si ti di pupọ: mo si kún nigbati mo ti gbà nkan wọnni ti a ti rán lati ọdọ nyin wá lọwọ Epafroditu, ọrẹ olõrùn didùn, ẹbọ itẹwọgbà, ti iṣe inu didùn gidigidi si Ọlọrun.

[19]. Ṣugbọn Ọlọrun mi yio pèse ni kikún fun gbogbo aini nyin, gẹgẹ bi ọrọ̀ rẹ̀ ninu ogo ninu Kristi Jesu.

[20]. Ṣugbọn ogo ni fun Ọlọrun ati Baba wa lai ati lailai. Amin.

ITUPALẸ:

Ipese Ọlọrun maa n sopọ mọ erongba Rẹ lọpọ igba. Ti o ba pe wa si iṣẹ kan pataki, Oun yoo pese ohun gbogbo ti a nilo lati ṣe aṣepe rẹ. (Filip. 4:19). Ṣugbọn, o ṣe pataki lati ranti pe ipese Rẹ wa fun ohun ti o ti fi lọlẹ, ki iṣe ohun ti a ti bẹrẹ laaye ara wa
(Isa. 55:10-11).

Ti a ba n ṣiṣẹ ninu iṣẹ ti Ọlọrun fun wa, ki a gbagbọ pe Oun yoo pese ohun gbogbo ti a nilo (2 Kọr. 9:8). Eyi ko tumọ si pe ko ni si ipenija tabi asiko inira, ṣugbọn, o tumọsi pe a le ni igboya ninu pe awọn ohun elo Ọlọrun yoo to (Efe. 3:20). Ipese Rẹ le wa ni awọn ọna ti a ko reti, ṣugbọn o maa n wá ni asiko ti o yẹ (Oniw. 3:1, 11).

Bi a ba ri i pe a ṣe alaini ohunkohun, akoko ti o dara ni ki a duro, ki a wa wadii boya a n ṣiṣẹ ni ibamu pẹlu eto Ọlọrun (Owe 3:5-6). Ṣe ọna Rẹ ni a n tọ̀, tabi a ti ya bàrá si agbekalẹ ara wa? Ti a ba wa ninu ifẹ Ọlọrun,ki a fọkanbalẹ pe Oun yoo ba gbogbo aini wa pade (Mat. 6:33).

Awọn koko Adura

1. Oluwa, ran mi lọwọ lati maa fi suuru duro de ipese Rẹ t**i yoo fi tẹ mi lọwọ.

2. Oluwa, ran mi lọwọ lati so gbogbo aye mi pẹlu erongba Rẹ.

3. Oluwa, mo gbagbọ ninu Rẹ pe Iwọ yoo ba gbogbo aini mi pade bi mo ti n rin ninu eto Rẹ.

Orin Ti A Dabaa Fun Oni:
CACGHB 71

ORIN IKỌKANLELADỌRIN

7 7 7 7

Nitoriti anu Rẹ duro laelae. OD. 136:1

1. Eje k'a f'inu didun
Yin Oluwa Olore
Anu Re, O wa t**i
Lododo dajudaju

2. On nipa agbara Re
F' imole s'aye titun
Anu Re, O wa t**i,
Lododo dajudaju,

3. O mbo gbogb' eda 'laye,
O npese fun aini won,
Anu Re, O wa t**i
Lododo dajudaju

4. O bukun ayanfe Re
Li aginju iparun
Anu Re, O wa t**i
Lododo dajadaju

5. Eje k'a f'inu didun
Yin Oluwa Olore,
Anu Re, O wa t**i
Lododo dajudaju

Amin.

Afikun Ibi Kika Fun Oni:
Lefitiku 4, 5, 6

30/01/2026

CHRIST APOSTOLIC CHURCH
[Nigeria and Overseas]

THE LIVING WATER (January-December, 2026)

DAILY DEVOTIONAL GUIDE

DATE:
Friday, 30th January, 2026

TOPIC:
THE GOD OF PURPOSE

MEMORISE

For I know the thoughts that I think toward you, says the Lord, thoughts of peace and not of evil, to give you a future and a hope (Jeremiah 29:11).

READ:
Jeremiah 29:10-14

[10]. For thus says the Lord: After seventy years are completed at Babylon, I will visit you and perform My good word toward you, and cause you to return to this place.

[11]. For I know the thoughts that I think toward you, says the Lord, thoughts of peace and not of evil, to give you a future and a hope.

[12]. Then you will call upon Me and go and pray to Me, and I will listen to you.

[13]. And you will seek Me and find Me, when you search for Me with all your heart.

[14]. I will be found by you, says the Lord, and I will bring you back from your captivity; I will gather you from all the nations and from all the places where I have driven you, says the Lord, and I will bring you to the place from which I cause you to be carried away captive.

EXPOSITION

God is a God of purpose. Everything He does is intentional and well-thought-out. When God created the world. He had a plan. When He called Abraham, He had a purpose for his life in the same way, God has a specific plan for each one of us. It is comforting to know that the God who sees the end from the beginning has already charted out the path we are to walk. But often, we may find ourselves striving to push our own plans, asking God to bless what we have designed. We take on projects, enter into commitments, or pursue ambitions that God never initiated. Then we wonder why we are not seeing His provision. The truth is, God only funds what He has launched. When we try to force things that aren't in line with His will, we step outside the covering of His divine provision

Are you trying to force a door open that God has closed? Today, spend time in prayer seeking to align your plans with God's purpose for your life. His plans are already blessed and provided for If we surrender our will to His, we will experience the fullness of His provision.

PRAYER POINTS

1. Pray that God will reveal to you when you go outside of His plans so that you can trace back your step into His plans.

2. Lord, help me not to force any door open that You have closed.

3. Lord, help Your Church in the land not to be working against Your purpose in any way.

SUGGESTED HYMN FOR TODAY:
CACGHB: 739

4 10 10 10 4

1. Come, labour on!
Who dares stand idle on the harvest plain,
While all around him waves the golden grain?
And to each servant does the
Master say,
"Go, work today!"

2. Come, labour on!
Claim the high calling Angels cannot share,
To young and old the Gospelgladness bear;
Redeem the time: its hours too swiftly fly,
The night draws nigh

3. Come, labour on!
The enemy is watching night and day
To sow the tears, to sn**ch the seed away;
While we in sleep our duty have forgot,
He slumber'd not.

4. Come, labour on!
Away with gloomy doubts and faithless fear!
No arm so weak but may do service here,
By feeblest agents can our God fulfil
His righteous will.

5. Come, labour on!
No time for rest, till glows the western sky,
Till the long shadows o'er our pathway lie,
And a glad sound comes with the setting sun
"Servants, well done!"

6. Come, labour on!
The toil is pleasant, the reward is sure,
Blessed are those who to the end endure;
How full their joy, how deep their rest shall be,
O Lord, with Thee!

Amen.

EXTRA READING FOR TODAY:
Exodus 36, 37, 38

30/01/2026

ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Naijiria àti Oke Okun

OMI IYE NAA, (January- December, 2026)

Ọjọ
ẸTI ( Friday) JANUARY 30, 2026.

ÀKÒRÍ:
ỌLỌRUN ERONGBA

AKỌSORI:

Nitori emi mọ̀ ìro ti mo rò si nyin, li Oluwa wi, ani ìro alafia, kì si iṣe fun ibi, lati fun nyin ni ìgba ikẹhin ati ireti (Jeremiah 29:11).

KA:
Jeremiah 29:10-14

[10]. Nitori bayi li Oluwa wi pe, Lẹhin ti ãdọrin ọdun ba pari ni Babeli, li emi o bẹ̀ nyin wò, emi o si mu ọ̀rọ rere mi ṣẹ si nyin, ni mimu nyin pada si ibi yi.

[11]. Nitori emi mọ̀ ìro ti mo rò si nyin, li Oluwa wi, ani ìro alafia, kì si iṣe fun ibi, lati fun nyin ni ìgba ikẹhin ati ireti.

[12]. Ẹnyin o si kepe mi, ẹ o si lọ, ẹ o si gbadura si mi, emi o si tẹti si nyin.

[13]. Ẹnyin o si ṣafẹri mi, ẹ o si ri mi, nitori ẹ o fi gbogbo ọkàn nyin wá mi.

[14]. Emi o di ríri fun nyin, li Oluwa wi: emi o si yi igbekun nyin pada kuro, emi o si kó nyin jọ lati gbogbo orilẹ-ède ati lati ibi gbogbo wá, nibiti emi ti lé nyin lọ, li Oluwa wi; emi o si tun mu nyin wá si ibi ti mo ti mu ki a kó nyin ni igbekun lọ.

ITUPALẸ:

Ọlọrun jẹ Ọlọrun erongba. Ohun gbogbo ti O ba n ṣe o n mọ-ọ-mọ ṣe e ni bẹẹni o si jẹ ero rere. Nigba ti Ọlọrun da aye, O ni ero. Nigba ti o pe Abrahamu, o ni erongba fun aye rẹ. Bakan naa, ni Ọlọrun ni ero/eto kan pato fun
ẹnikọọkan wa. O jẹ ohun itunu lati mọ pe Ọlọrun ti o ri opin lati ibẹrẹ ti la ọna ti a o tọ. Ṣugbọn lọpọ igba, a le ri ara wa ki a maa jijagudu lati gbe ero ti wa wọle, ki a si maa sọ fun Ọlọrun ki o sure si/bukun ohun ti a gbekalẹ. A maa n ṣe akanṣe iṣẹ, a o wọnu adehun tabi lepa ohun ti Ọlọrun ko fi lọlẹ. A wa maa ya wa lẹnu idi ti a ko fi ri ipese Rẹ. Otitọ ibẹ ni pe ohun ti Ọlọrun ba fi lọlẹ ni o n pese fun. Nigba ti a ba n gbiyanju lati fi agbara gbe ohun ti ko si ni ibamu pẹlu ifẹ Rẹ wọle, a o jade kuro labẹ asia ipese atọrunwa Rẹ.

Iwọ fẹ fi agbara si ilẹkun kan ti Ọlọrun ti ti bi? Lonii, lo akoko ninu adura ki o wa bi iwọ yoo ṣe so eto rẹ papọ mọ erongba Ọlọrun fun aye rẹ. Eto Rẹ ti gba ibukun tẹlẹ bẹẹni o si ti pese fun un. Ti a ba jọwọ ifẹ wa fun tiRẹ, a o ni iriri ẹkunrẹrẹ ipese Rẹ.

Awọn koko Adura

1. Gbadura pe ki Ọlọrun ki o fi han fun ọ igba ti o ba ti jade kuro ninu eto/ero Rẹ ki o ba a le ṣe atunṣe pada sinu eto Re.

2. Oluwa, ran mi lọwọ ki n maṣe fi agbara si ilẹkun Kankan ti O ti ti.

3. Oluwa, ran Ijọ Rẹ ni ilẹ yii lọwọ ki o maṣe maa ṣiṣẹ tako erongba Rẹ ni ọnakọna.

Orin Ti A Dabaa Fun Oni:
CACGHB 739

OJILELẸẸDẸGBẸRIN O DIN KAN

4 10 10 10 4

Lọ ṣiṣẹ loni ninu ọgba ajara mi.
-- Mat. 21:28

1. Wa, ma ṣiṣẹ,
Tani gbọdọ s'ole ninu oko
'Gbati gbogbo eniyan nkore jo,
Kaluku ni Baba pe fun ise;
“Sise loni”

2. Wa, ma sise,
Gba 'pe giga ti angeli ko ni
Mu 'hinrere to t'agba t'ewe lo,
Ra 'gba pada, wawa l'akoko nlo,
Ile su tan.

3. Wa, ma sise,
Oko po, alagbase ko si to,
Aye titun po fun wa lati kun,
Ohun ona jinjin, at'itosi
Nkigbe pe; “Wa”

4. Wa, ma sise
Le 'yemeji on aigbagbo jina,
K'o s'alailera ti ko le se nkan,
Ailera l'Olorun a ma lo ju '
Fun se nla Re

5. Wa, ma sise,
'Simi ko si nigbat' ise osan,
T**i orun yio fi wo l'ale,
Ti awa o si gbo ohun ni pe:
“O seun, omo”

6. Wa, ma sise,
Lala na dun ere re si daju,
'Bukun f'awon t'o f'ori ti d'opin
Ayo won, 'simi won y'o ti po to!
“Lo d' Oluwa”

Amin.

Afikun Ibi Kika Fun Oni:
Eksodu 36, 37, 38

Address

Onitapoli Village
Ilesa

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Ori-Oke Majemu Emi-Oluwa Ministries posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Share