20/08/2026
IGBIMO OGUN TIN JAYE OMO OLOGO APA KETA NTE SIWAJU
AIROMOBI: Eyi je okan gbogi ninu oro ti a nso yi. Nigbati omobinrin ba se igbeyawo tan ohun ti opan sunkan ni wipe ki o fi inu soyun ko si fi eyin re gbomi pon. Sugbon kaka ki o fi ri bee ekun adasun ni o ma sun ni gbogbo igba. Wa gbomi Iwo eda to wa niru ipo yi k'odun yi to Pari wa rerin Ayo loruko jesu. Kere, kere o ma ti to odun meta merin, nigba to ba ya awon ebi oko won ma gbe idamu dide si iyawo omo won. Bi won ti n soro buburu si, ni won ma fi we nkan ti ko dara. Nje Iwo tile ronu Nipa Oro wonyii? Se o tile bi eleda re lere ki o to Yan gan? Ai bere lowo eleda won lo ma pelu nkan to ma fa, ti opo enia ko fi Tete ri idahun gba. Ki won to yan awon miran bere sugbon won si bere nitori won o ma bi won nse gba adura. Mo fe ki o lo gbe bibeli re ki o lo si iwe (1 Samuel 1 v1---18) ninu eko ti a ka yen a ri wipe olorun ma, ma Se Hannah ninu ni, mo si Fe ki o mo pe, o ti pe ti Hannah ti nlo si Shiloh sugbon ko mu igbagbo re Dani. Ama lojo to ronu re wipe aaye to oun wa yi ko te oun lorun, o ba eleda re soro o si gbo. Mo fe ki o mo pe, ti ki nba se pe ipin ti oko re fun nigbati won lo si Shiloh ni, Hannah hi ba ma Tete ronu re rara, nitori bibeli so wipe (1 Samuel 1v4---5) Hannah ni o fun ni ipin meji nitori ti o nife re sugbon ko bimo. Mo gba ladura pe oruko buburu t'aye fi npe o yen Loni yi baba mi orun yi won pada si rere loruko jesu. Se o wa ri wipe agan ojosi pada wa Di olomo meje (1 Samuel 2, v5 ) mo wa gba ladura pe Iwo okan to wa niru ipo yi k'odun yi to Pari wa rerin Ayo loruko jesu amin.
WO SARE GBA ADURA YII
Oba to siju wo Hannah gbato lo si Shiloh, oluwa siju Aanu re womi l'odun yi loruko jesu
KORIN YII: Aanu ni mo bere baba, Aanu ni mo bere awijare ma ko o Aanu ni mo bere
Oba to so Egan Hannah dogo, so egun aye mi dogo k'odun yi to Pari loruko jesu
Oba to fi Aanu wa Sara ri, f'anu re fami jade kuro ninu ipo airomobi yi loruko jesu Ami.
APA KERIN
"OGUN ABIJO".