25/04/2022
Psalms 130:1-8
[1]LATI inu ibu wá li emi kepe ọ, Oluwa.
(A Song of degrees.) Out of the depths have I cried unto thee, O LORD.
[2]Oluwa, gbohùn mi, jẹ ki eti rẹ ki o tẹ́ silẹ si ohùn ẹ̀bẹ mi.
Lord, hear my voice: let thine ears be attentive to the voice of my supplications.
[3]Oluwa, ibaṣepe iwọ a mã sami ẹ̀ṣẹ, Oluwa, tani iba duro?
If thou, LORD, shouldest mark iniquities, O Lord, who shall stand?
[4]Nitori idariji wà lọdọ rẹ, ki a le ma bẹ̀ru rẹ.
But there is forgiveness with thee, that thou mayest be feared.
[5]Emi duro dè Oluwa, ọkàn mi duro, ati ninu ọ̀rọ rẹ̀ li emi nṣe ireti.
I wait for the LORD, my soul doth wait, and in his word do I hope.
[6]Ọkàn mi duro dè Oluwa, jù awọn ti nṣọ́na owurọ lọ, ani jù awọn ti nṣọ́na owurọ lọ.
My soul waiteth for the Lord more than they that watch for the morning: I say, more than they that watch for the morning.
[7]Israeli iwọ ni ireti niti Oluwa: nitori pe lọdọ Oluwa li ãnu wà, ati lọdọ rẹ̀ li ọ̀pọlọpọ idande wà.
Let Israel hope in the LORD: for with the LORD there is mercy, and with him is plenteous redemption.
[8]On o si da Israeli nidè kuro ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gbogbo,
And he shall redeem Israel from all his iniquities.