07/08/2026
ỌJỌ́ ẸTÌ (FRIDAY),
7 AUGUST, 2026
Kíkọ Nínú Ìwé Orin ECWA: EHB 482
IBI KÍKÀ: ÌFIHÀN 12:10-17
KÓKÓ ẸKỌ: ÀJỌYỌ PÉ ALÉ OLÙFISÙN KÚRÒ NÍ ỌRUN
ÌFIHÀN 12:10-17
10 Mo si gbọ́ ohùn rara li ọrun, nwipe, Nigbayi ni igbala de, ati agbara, ati ijọba Ọlọrun wa, ati ọla ti Kristi rẹ̀; nitori a ti lé olufisùn awọn arakunrin wa jade, ti o nfi wọn sùn niwaju Ọlọrun wa lọsán ati loru.
11 Nwọn si ṣẹgun rẹ̀ nitori ẹ̀jẹ Ọdọ-Agutan na, ati nitori ọ̀rọ ẹrí wọn, nwọn kò si fẹran ẹmi wọn ani t**i de ikú.
12 Nitorina ẹ mã yọ̀, ẹnyin ọrun, ati ẹnyin ti ngbé inu wọn. Egbé ni fun aiye ati fun okun! nitori Èṣu sọkalẹ tọ̀ nyin wá ni ibinu nla, nitori o mọ̀ pe ìgba kukuru ṣá li on ni.
13 Nigbati dragoni na ri pe a lé on lọ si ilẹ aiye, o ṣe inunibini si obinrin ti o bí ọmọkunrin na.
14 A si fi apá iyẹ́ meji ti idì nla na fun obinrin na, pe ki o fò lọ si aginjù, si ipò rẹ̀, nibiti a gbé bọ́ ọ fun akoko kan ati fun awọn akoko, ati fun idaji akoko kuro lọdọ ejò na.
15 Ejò na si tú omi jade lati ẹnu rẹ̀ wá bi odo nla sẹhin obinrin na, ki o le mu ki ìṣan omi na gbá a lọ.
16 Ilẹ si ràn obinrin na lọwọ, ilẹ si yà ẹnu rẹ̀, o si fi ìṣan omi na mu, ti dragoni na tú jade lati ẹnu rẹ̀ wá.
17 Dragoni na si binu gidigidi si obinrin na, o si lọ ba awọn iru-ọmọ rẹ̀ iyokù jagun, ti nwọn npa ofin Ọlọrun mọ́, ti nwọn si di ẹrí Jesu mu.
ÀJỌYỌ PÉ ALÉ OLÙFISÙN KÚRÒ NÍ ỌRUN
Ayé wá kún fún ìrora àti ìbànújẹ́ èyí tí Sátánì àti àwọn ẹ̀mí òkùnkùn rẹ̀ ṣe okùnfà rẹ̀. Ìròyìn búburú wà ní ibi gbogbo, ó sì ti mọ́ àwọn ènìyàn lára toríopé wọn tí yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Láìsí Ọlọ́run, Èṣù ni eniyan a súnmọ́. Kò ya ọ̀pọ̀ àwọn adaríwa lẹ́nu níti àwọn ìsẹ̀lẹ̀ náà. Bí wọn ti ń bá àwọn ẹgbẹ́ bí Boko Haram àti Awọn ajínigbé jà, wọ́n tún dákún ìṣòro náà nípa jíjìnnà sì àwọn ẹ̀kọ́ Ọlọ́run.
Èṣù ti tan ọ̀pọ̀ jẹ. Kò yani lẹ́nu pé àwọn áńgẹ́lì ń yọ̀ ní ọ̀run nígbà tí a le Sátánì sì ayé (ẹsẹ 10-11), lékè gbogbo ìkìlọ̀, “ègbé ni fún àwọn olùgbé ayé” (ẹsẹ 10-12).
ÌBÉÈRÈ:
Kíni o lè ṣe láti dá ìkọlù Drágónì dúró lórí ìran ènìyàn?
ÀDÚRÀ:
Olúwa, jẹ́ kí iná ìjèrè-ọkàn máa jò nínú mi, kí O sì rànmí lọ́wọ́ láti pín ìyìnrere ìgbàlà pẹ̀lú gbogbo ẹni tí mo bá bá pàdé ní orúkọ Jésu, Àmín.
ÓÙNJẸ ÒÒJỌ́