28/08/2026
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Naijiria àti Oke Okun
OMI IYE NAA, (January- December, 2026)
Ọjọ Ẹti (Friday), August 28, 2026.
ÀKÒRÍ:
TITẸSIWAJU SII PẸLU JESU (3)
AKỌSORI:
Ẹ mã ṣọna, ki ẹ si mã gbadura, ki ẹnyin ki o má ba bọ sinu idẹwò: lõtọ li ẹmi nfẹ ṣugbọn o ṣe alailera fun ara (Matiu 26:41).
KA:
Matiu 26:36-47
[36]. Nigbana ni Jesu bá wọn wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane, o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi nigbati mo ba lọ igbadura lọhúnyi.
[37]. O si mu Peteru ati awọn ọmọ Sebede mejeji pẹlu rẹ̀, o si bẹ̀rẹ si banujẹ, o si bẹ̀rẹ si rẹ̀wẹ̀sì.
[38]. Nigbana li o wi fun wọn pe, Ọkàn mi bajẹ gidigidi t**i de ikú: ẹ duro nihinyi, ki ẹ si mã ba mi sọ́na.
[39]. O si lọ siwaju diẹ, o si dojubolẹ o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi o ba le ṣe, jẹ ki ago yi ki o kọja kuro lori mi, ṣugbọn kì í ṣe bi emi ti nfẹ, bikoṣe bi iwọ ti fẹ.
[40]. O si tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o bá wọn, nwọn nsùn, o si wi fun Peteru pe, Kinla, ẹnyin ko le bá mi ṣọ́na ni wakati kan?
[41]. Ẹ mã ṣọna, ki ẹ si mã gbadura, ki ẹnyin ki o má ba bọ sinu idẹwò: lõtọ li ẹmi nfẹ ṣugbọn o ṣe alailera fun ara.
[42]. O si tún pada lọ li ẹrinkeji, o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi ago yi kò ba le ré mi kọja bikoṣepe mo mu u, ifẹ tirẹ ni ki a ṣe.
[43]. O si wá, o si tun bá wọn, nwọn nsùn: nitoriti oju wọn kun fun orun.
[44]. O si fi wọn silẹ, o si tún pada lọ o si gbadura li ẹrinkẹta, o nsọ ọ̀rọ kanna.
[45]. Nigbana li o tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o si wi fun wọn pe, Ẹ mã sùn wayi, ki ẹ si mã simi: wo o, wakati kù fẹfẹ, ti a o si fi Ọmọ-ẹnia le awọn ẹlẹṣẹ lọwọ.
[46]. Ẹ dide, ki a mã lọ: wo o, ẹniti o fi mi hàn sunmọ tosi.
[47]. Bi o si ti nsọ lọwọ, wo o, Judasi, ọkan ninu awọn mejila de, ati ọ̀pọ enia pẹlu rẹ̀ ti awọn ti idà pẹlu ọgọ lati ọdọ awọn olori alufa ati awọn àgba awọn enia wá.
ITUPALẸ:
Ni Getsemane, Jesu koju ipenija ti o ga julọ ninu iṣẹ iranṣẹ Rẹ ninu Ayé. O mú awọn ọmọ ẹyin mọkanlá yokù pẹlu Rẹ. Bi wọn ti n lọ, Jesu sọ fun ọmọẹyin mẹjọ ninu wọn lati duro ni oju kan nigba ti O lọ siwaju pẹlu awọn mẹta míran- Peteru. Jakọbu ati Johanu-- awọn ẹniti ti o gbagbọ lati ràn An lọwọ Awọn ọmọ ẹyin mẹjọ yẹn ni a kò fún ni iṣẹ kan pàtó lati ṣe ju pé ki wọn dúró. Mo lérò pé iwọ kii ṣe alaiṣiṣẹ ati onigbagbọ ti a ti ge kúrò, ti o kùnà lati ni ifaraji si nini ibarinpọ ti o jinlẹ pẹlu Kristi.
Awọn mẹta ti wọn tẹsiwaju ni anfaàni lati fi oju ri ibanujẹ ati idaamu ọkan Jesu. Akókò iṣẹlẹ ojú mi lo ṣe yii ṣe afihan bi Jesu ṣe fẹ oye ati atilẹyin wọn tó. Ọpọlọpọ Kristiẹni lónii kùnà lati mọ bi ifẹ ọkàn wọn ṣe n ni ipa lori ibaṣepọ wọn pẹlu Kristi. Jesu ṣe ibapin ẹru wuwo Rẹ pẹlu awọn mẹta O si rọ wọn ki wọn maa ṣọna ki wọn si maa gbadura -jiji giri ninu ẹmi ati ojuṣe.
Ṣugbọn ó ba-ni-ninú-jẹ pé, awọn ọmọ ẹyin mẹta náà sùn dipo ki wọn maa ṣọna, eyi n rán wa leti àilera eniyan ati pataki wíwà ni iduró gangan ninú irin-àjò wa. Ojuṣe ninú ijọba Ọlọrun jẹ anfaani ti o nilo ifaraji. Ẹ jẹ ki a ji ninu ẹmi ki a si tẹsiwaju pẹlu Jesu nipa adura igba gbogbo pẹlu iyasọtọ.
Awọn koko Adura
1. Oluwa, ràn mi lọwọ lati faraji ninu ẹmi ninu irin mi pẹlu Rẹ.
2. Baba, dariji mi fun awọn akoko ti mo ti kùnà ninu ojuṣe mi si Ọ.
3. Jesu Olúwa, fún mi ni oore-ọfẹ lati maa ṣọna ki n si maa gbadura nigba gbogbo.
Orin Ti A Dabaa Fun Oni:
C.A.CGHB: 571
ỌRINLELẸẸDẸGBẸTA O DIN MẸSAN
10 10
O yẹ ki enia ma gbadura nigbagbogbo lai simi ati lai ṣarẹ .
Lk. 18:1
1. Ma gbadura; Emi mbebe, n'nu re,
Fun gbogbo aini re igba-gbogbo.
2. Ma gbadura; l'abe eru ese,
Adura nri eje Jesu ti nsan.
3. Ma gbadura; b'are tile mu O,
Adura ngbe wa s'eba 'te Baba.
4. Ma gbadura; n'nu wahala aye,
Adura l'o nfun okan n'isimi.
5. Ma gbadura; b'ayo ba yi o ka,
Adura nlu harp o nkorin angel'.
6. Ma gbadura b'awon t'o feran ku,
Adura mba won mu omi iye.
7. Gbogb' ohun aye y'o b'aye koja,
Adura wa t**i; ma gbadura.
Amin.
Afikun Ibi kika Fun Oni:
Jeremáyà 21-23