22/01/2013
EKO NINU IWE ESTERI (EKO KEJE)
IBI KIKA: Est. 2: 1 - 18. 21/01/2013 AKOSORI: Joh. 3:27
ESTERI DI AYABA
Ninu eko yii ni a yoo ri ifarahan agbara nla Olorun lori iseda eniyan.
Olorun ninu agbara n la Re ti mu enikan ti je eni n la ti o si ni agbara (Fasti) kuro ni ipo giga. re gegebi ayaba o si wu Olorun yii kanna lati gbe eni ti o wa ni ipo irele (Esteri) ga si ipo giga 1Sam. 2: 6-8; Lk. 1: 52; 1Sam.16:11-12. A nilati mo gegebi onigbagbo pe ipokipo ti a ba wa bayii, Olorun mo ati wipe a nilati lo ipo bee pelu irele fun ogo Olorun nitori nigbose, yoo gbe wa ga.1Pet. 5:6.
1. WIWA AYABA TUNTUN. Est. 2:1-14.
* Oba pase ki a ko gbogbo wundia ti o lewa jo, ki a si ko won wa si Susani aafin lati owo olori igberiko kookan ijoba Ahaswerusi.
* Oluwa wa lati wa ati lati gba awon aguntan ti o nu la. O si ran gbogbo awon omo ehin Re gegebi a ti ran an. Ezek. 34:16; Lk. 19:10; Jh. 15:16; 20:21.
* Awon wundia ti o ni anfaani lati di ayaba wonyii ni a pamo labe abojuto Hegai lati pese won sile ati lati mu won wa ni mimo ati ni imurasile fun oba.
* Gbogbo onigbagbo kookan ni a n pese sile, we mo ati wa ni imurasile fun Olorun (iyawo) lati owo Emi mimo nipa ase ati eko oro Olorun ninu ijo. Mat. 28:18-20; Ise 2:42; Efe. 5: 24-27; Tit. 2: 11-15; Heb. 12:13-17.
2. A YAN ESTERI LATI JE AYABA. Est. 2:4-7.
Esteri, alaini obi sugbon ti ati owo Mordekai egbon re to dagba, je arewa ti o dun lati wo ni a mu wa si ile oba niwon bi ko ti lee fi ara re pamo.
* Modekai gegebi alagbato Esteri (irawo), ko ni omo ati gegebi a ti gbe lo ni igbekun lo si Babiloni lati owo Nebukadinasari ko gbagbe ibatan re Esteri. Bawo ni Modekai ati ibatan re se dee Susani aafin oba lati ile Babiloni. Ko ni ero wipe Esteri yoo wulo fun oun ni aye, melomelo igbega nipase re si ipo keji ni ijoba Ahasuwerusi. N je o je mo wipe enikan na ti o le je arakunrin tabi arabinrin egbon re okunrin tabi obinrin ti o ko lati je iranwo fun tabi ti o ran lowo, le je ohun elo tabi ona si igbega re tabi isubu re. Oniw.11:1-2; Ise 23: 15-22.
MODEKAI MU ESTERI LATI DARAPO MO AWON AREWA TI A FE YAN GEGEBI AYABA. Esteri 2:8.
Laisi awawi Modekai je osise (asona) ni Susani aafin. Modekai gbo nipa ofin oba nipa idije ekinni fun awon arewa odomobinrin ninu iwe mimo ni susani aafin, nibiti a ti ko opolopo odomobinrin jo. O sese pe oun ni o yan Esteri ti oun pelu re ma n sun ni ibode pelu re lati kopa ni idije na. Opolopo eko ni igbese yi ko ni.
* Modekai ko ko iyan ara re kere gegebi alaiye, tabi gegebi asobode ni aafin.
* Modekai gbagbo gegebi ju eya Benjameni gbagbo pe oun le se aseyori ninu ohunkohun pelu Olorun. Gen.11:6. Ti o ba wa ni inu kan pelu Olorun ninu odun yi, iwo yo o ri ona abayo lopolopo.
* Nipa igbagbo ko sai ka Esteri si eniti o je eru ti o si yan lati kopa ni idije gegebi ayaba.
* Ninu gbogbo n kan wonyi Olorun n se ise abo awon Ju kuro lowo iparun Hamani.
* Iwo ore mi n je o mo wipe wiwa re ni ijo C.F.F.M. fun idi kan ni, se ohun gbogbo nipa agbara re lati mu ki eto Olorun ko wa si imuse lori aye re.
* Ti a ba n gbe igbe aye wa lona otito, ododo ati ni iberu Olorun, imole wa yoo tan ni ibikibi ti a ba wa. Mat.5: 13 -16.
* Esteri ba ojurere Hegai pade, (1) A si fun un ni ohun gbogbo ti o nilo fun iwenumo laisi idaduro kankan. (2) A fun un ni awon n nkan ti o je tire, iransebinrin meje lati maa se iranse fun un ati (3) Ibi ti o dara julo ni ile awon obinrin. Est. 2: 9, 15. (4) * Agbara Olorun sise ni igba aye Hegai. (5) Esteri ri ojurere lati odo Olorun lati pa awon Ju mo.
* Ni rinrin ninu ofin Olorun, ni diduro ti aanu ati otito, a o yoo ri ojurere lodo Olorun ati eniyan. Owe 3:1-4. Gegebi o ti ri fun Josefu. Gen. 39: 6, 21 ati pelu fun Jesu Oluwa wa. Luk. 2: 52.
KOKO ORO: - SE IWO YE LATI KOPA NI IDIJE EWA TI ORUN? Ifi. 19:7.