24/02/2023
OGUN MERIN TI ONIGBAGBO NJA NINU AYE YI.
Text, Efesu,6:12. Nitori pe ki i se EJE ati eran Ara ni awa n ba jijakadi, sugbon awon ijoye, awon olola, awon Alase ibi okunkun aye Yi ati awon emi buburu oju orun.
Awon Ogun ti a ndoju ko ninu aye ni wonyi.
(1). Awon ijoye. Awon wo ni ijoye, awon eleyi ni awon ti o je oye ninu ijoba okunkun gege bi aje(witches) ati oso,(wizards), ninu aye Yi naa ni a Jo ngbe. Awon wonyi a maa Fe lΓ ti Dan agbara wo Lara eniyan ni gbogbo ONA ti eniyan ngba lati je eniyan ni awon ijoye wonyi ma Fe lΓ ti Daru, tabi mi IDADURO ba lojiji labe idajo agbara won
(2). Awon olola. Awon wonyi je eniti Olorun ti bukun fun ti ko si Fe ki elomiran je nkankan ju awon lo, awon Yi ki I ran eniyan lowo lati SE ohun rere. Ohun ti won le fun KONI yanju isoro to ba e de Odo won. Awon lo nje aminusin.
(3). Awon Alase ibi okunkun. Awon wonyi ni agbara ati emi airi bi, Mami water, awon to ngbe Inu igi, okuta, Ina ati ninu aginju.
Awon wonyi lo ma n mu eniyan LA ALA pe ohun nwe ninu Omi NLA, ibalopo ati ounje oju orun, ninu eyi ti oko ati Aya orun n FARAHAN. Awon wonyi a maa fi Ase Oro de eniyan sojukan fun ojo pipe, be e ni won a ma a da ise iranse tabi ti oojo eniyan RU patapata..
(4) Awon emi buburu oju orun. Awon eleyi a ma a de na adura eniyan. Nitori EMI pupo lo wa ni oju Orun sugbon Emimimo koja oju orun ninu orun ni ohun ngbe.
Awon emi buburu wonyi ni ti balogun pasia.to ndena opolopo lati ri idahun si ibeere won ninu adura. Sugbon ORUKO JESU OLUGBALA lo n fun WA lagbara lati bori won, ti awon emi wonyi ba bere ise Lori eniyan, tabi ebi kan won a ri pe won ba ebi tabi eniyan naa kanle lofifo.
Emimimo ti fun WA ni Oro iyanju lati bori gbogbo awon Ogun ni ESE kewa iwe Efesu 6:10 Lakotan Ara EJE alagbara ninu Oluwa, ati ninu agbara IPA re. Lai si agbara ati Oluwa ninu aye eniyan, enikeni kole bori. Mo gbadura pe agbara Oluwa pelu IPA re lati bori Olorun Yi o gbe wo wa loruko Jesu AMIN.